Ogun eeyan pere ni mo ṣi pa laye mi, ẹ fori jin mi - Wasiu K-Federal, ogbologbo ọmọ ẹgbẹ okunkun tọwọ tẹ l'Ọṣun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, May 12, 2023

Ogun eeyan pere ni mo ṣi pa laye mi, ẹ fori jin mi - Wasiu K-Federal, ogbologbo ọmọ ẹgbẹ okunkun tọwọ tẹ l'Ọṣun


Beeyan ba wa nibi ti ogbologbo ọmọ ẹgbẹ okunkun apaniṣaye tọwọ tẹ nipinlẹ Ọṣun laipẹ yii ṣe n sọrọ, to si n jẹwọ awọn iwa ika to ti hu, yoo mọ pe ọdaran paraku ni, ko si loju aanu rara.
 
Saheed Wasiu, tọpọ awọn eeyan mọ si K-Federal, ẹni t'awọn ọlọpaa ti n wa tipẹ lọwọ palaba rẹ segi, lọjọ keje, oṣu karun-un, ọdun ti a wa yii.

A gbọ pe ọpọ awọn eeyan ni K-Federal ti da ẹmi wọn legbodo nitori iwa ẹgbẹ okunkun to wa ninu rẹ.
 
Gẹgẹ bi agbẹnusọ f'awọn ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun, Yẹmisi Ọpalọla ṣe ṣalaye f'awọn akọroyin, o ni agbegbe Aluṣẹkẹrẹ to wa niluu Ẹdẹ lọwọ awọn ti tẹ K-Federal.
 
Bẹẹ lo jẹ ko di mimọ pe ọkan gboogi ni K-Federal ninu ẹgbẹ okunkun Ẹiyẹ, eyi ti Raṣheed Hammẹd, ẹni t'awọn eeyan tun mọ si Ọkọ-Ilu jẹ alakoso rẹ.
 
Ọpalọla ni bo tilẹ jẹ pe olori wọn, Ọkọ-Ilu ti wa lahamọ wọn tipẹ, to si ti wa lọgba ẹwọn, o ni sibẹ, awọn ko dẹkun lati rọwọ to awọn ogbologbo to tun n da igboro laamu, bii K-Federal.
O wa sọ pe Wasiu K-Federal ti jẹwọ pe lotitọ loun n ṣẹgbẹ okunkun, ati pe ogun eeyan pere loun ti pa danu niluu Ẹdẹ, toun si ti ju oku wọn sinu odo Ọṣun to wa lagbegbe Sagba, niluu Ẹdẹ.
 
Lara awọn to ti pa danu ni Wale, Jamiu, Ganiyu, Azeez, Eyimba atawọn miran ti a ko le darukọ tan lasiko yii.
 
Ọpalọla ti wa jẹ ko di mimọ pe awọn yoo foju rẹ ba ile ẹjọ lẹyin ti iwadii ba tubọ pari.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI