O ma ṣe o! Wọn ba oku iyaale ile ti wọn jigbe ninu igbo, lẹyin ti wọn san miliọnu mẹfa naira - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, May 6, 2023

O ma ṣe o! Wọn ba oku iyaale ile ti wọn jigbe ninu igbo, lẹyin ti wọn san miliọnu mẹfa naira


Titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii, inu ibanujẹ nla l'awọn mọlẹbi iyaale ile kan to n tọmọ oṣu mẹrin lọwọ, Kẹhinde Ikẹanabi Jibril, tawọn ajinigbe jigbe laipẹ yii wa, lori bi wọn ṣe ṣeku pa obinrin naa.
 
Ọjọ meji si ọjọ ọdun Itunnu Aawẹ la gbọ pe wọn ji Kẹhinde gbe niluu Agọ-Ọja to wa nitosi ilu Ilọrin, ipinlẹ Kwara, ti wọn si n beere obitibiti owo to le ni miliọnu naira.
 
A gbọ pe awọn mọlẹbi ko ri owo ti awọn ajinigbe naa n beere, ṣugbọn ti wọn pada ri miliọnu mẹfa naira lati tu jọ.
 
Lẹyin ti wọn lọ gbe miliọnu mẹfa naa silẹ f'awọn ajinigbe la gbọ pe wọn ba oku rẹ lẹgbẹ igbo kan to wa loju ọna Ojoku, iyẹn niluu Agọ-Ọja ọhun l'Ọjọbọ, tii ṣe Tọsidee.
 
Kehinde Ikeanabi Jibril la gbo pe awon ajinigbe tun jigbe lose to kọja lọhun lagbegbe Oketu niluu Ago-Oja to wa nitosi ilu Ilorin.
 
A gbo pe nnkan bi aago kan oru ni won wole to obinrin naa, ti won si jii gbe, bo tile je pe won fi omo to n to lowo ati akobi re sile lo ni.
 
Gege bi iroyin to te wa lowo se so, won ni oko obinrin naa, Alaaji Isiaka Oloye Jagun Street, eni ti won lo n ta maluu, to si tun je olori egbe alajeseku kan to gbajumo daadaa lawon ajinigbe naa wa lo sile re lati jiigbe.
 
Bi won ko se ba a nile lojo naa lo mu ki won ji iyawo re, Kehinde gbe salo, ti won si n beere fun milionu mewaa naira ko to di pe won tu sile lahaamo won.
 
Won ni Ojoru tii se Wesidee saaju ojo Itunu Aawe to koja yii ni isele ohun waye, ti awon eeyan si n kominu lori isele naa titi di asiko ti a pari akojopo iroyin yii.
 
Baale agbegbe naa, Malaam Daudu Salaudeen Arolu, nigba to n kominu lori isele ohun so pe inu iberubojo lawon wa, nitori pe awon ko le rin bo se wu won mo niluu, bee lo so pe awon kii sun laaarin oru mo bayii, to si rawo ebe s’awon ileese eleto aabo, paapaa ijoba lati dide iranlowo fun won.
 
Baale naa so pe saaju ojo naa ni won ti ji gendekunrin akekoo ile eko gbogbonise tipinle Kwara gbe, ti won si lu omokunrin naa nilu baraa, ko to di pe won gba owo, eyi to mu ki won pada tu sile.
 
O ni inu ile to n gbe ladugbo Abiye ni Ago-Oja ni won ti lo jiigbe, to si ni egberun lona irinwo naira ni won gba lowo awon eeyan re.

Siwaju sii lo ni won tun ji enikan naa gbe lojo Good Friday to koja lo, to si ni egberun lona igba naira lo din ninu milionu meta naira ti won n gba lati tu eni naa sile.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI