Wọn ju dọkita satimọle n'Ilọrin, nọọsi to wa gba itọju ni wọn lo f'ipa ba laṣepọ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, May 12, 2023

Wọn ju dọkita satimọle n'Ilọrin, nọọsi to wa gba itọju ni wọn lo f'ipa ba laṣepọ


Ile ẹjọ Majisireeti to wa niluu Ilọrin, ipinlẹ, Kwara ti ju gbajugbaja oniṣegun oyinbo kan, Dọkita Ayọdele Joseph satimọle lori ẹsun ifipabanilopọ.
 
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, wọn ni ẹni to wa gba iwosan lọsibitu ti Dọkita Ayọdele ti jẹ ọga agba, iyẹn ile iwosan Ayọdele to wa lagbegbe Sawmill niluu Ilọrin lo ti ṣiṣẹ buruku naa.

Wọn ni nọọsi ni ẹni ti Ayọdele, ẹni to loun ti lo ọdun mẹtadinlọgbọn lẹnu iṣẹ naa fipa ba laṣepọ, ati pe niṣe lo gun obinrin naa labẹrẹ oorun ko to fipa ba a laṣepọ.
 
Ẹsun ti wọn fi kan Ayọdele ni wọn lo tako iwe ofin ọdaran, abala 285 ati 283, to si ni ijiya ninu.

A gbọ pe fọnran to fidi bi Ayọdele ṣe fipa ba obinrin naa laṣepọ tẹ ile ẹjọ lọwọ, bẹẹ ni ayẹwo tun fidi rẹ mulẹ pe lotitọ ni ọkunrin naa fipa ba nọọsi ọhun laṣepọ.
 

Nigba to n fẹsun kan Ayọdele niwaju ile ẹjọ, agbefọba Gbenga Ayẹni sọ pe iwadii ọlọpaa fidi mulẹ daadaa, ti idajọ ododo si gbọdọ waye.

Onidajọ Gbadeyan Jumọkẹ Kamson wa paṣẹ pe ki Ayọdele ṣi wa lahamọ awọn ọlọpaa titi di ọjọ kejidinlogun, oṣu karun-un, ọdun ti a wa yii, ti idajọ yoo tun pada waye.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI