Wọn ju 'Ọmọ Yahoo' mẹrin sẹwọn n'Ilọrin - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, May 12, 2023

Wọn ju 'Ọmọ Yahoo' mẹrin sẹwọn n'Ilọrin


Ile ẹjọ giga to wa niluu Ilọrin, ipinlẹ Kwara ti ju awọn gendekunrin mẹrin kan sẹwọn lori ẹsun jibiti ori ayelujara ti a mọ si 'Yahoo-Yahoo' pẹlu iṣẹ aṣekara.

Ajọ to n gbogun ti iwa jibiti ati ajẹbanu lorileede yii, Economic and Financial Crimes Commission, EFCC, lo fẹsun kan awọn mẹrin naa, niwaju Onidajọ Mahmoud Abdulgafar.
 
Ninu atejade ti ajọ EFCC gbe jade l'Ọjọbọ ti ṣe Tọsidee, ọsẹ yii, wọn darukọ awọn mẹrin naa gẹgẹ bii Dauda Sọliu Tunde, Lambẹ Taiye, Ọmọgbọlahan Ibrahim Wasiu ati Ọlọrunfẹmi Ayọbami.
 
Ṣaaju idajọ naa lawọn mẹrin yii ti jẹwọ pe lotitọ lawọn jẹbi ẹsun ọtọọtọ ti wọn fi kan wọn, ṣugbọn ti bẹbẹ fun oju aanu.
 
Awọn agbefọba meji to tako awọn mẹrẹẹrin niwaju Onidajọ, Ṣẹsan Ọla ati Mukhtar Kaigama ṣalaye pe iwadii ijinlẹ lawọn ajọ EFCC ṣe ko to di pe aṣiri wọn tu.
 
Wọn jẹ ko di mimọ pe awọn gba foonu, kọmputa alagbeka ti wọn fi n ṣiṣẹ burulu lọwọ wọn lọjọ tọwọ palaba wọn segi.
 
Onidajọ Abdulgafar ju Dauda sẹwọn oṣu mẹfa gbako pẹlu iṣẹ aṣekara, ati pe awọn alakoso ọgba ẹwọn Mandala gbọdọ mojuto o fun iwa ọmọluabi. Bẹẹ lo paṣẹ pe ki Dauda gbagbe foonu iPhone 11 ati iPhone 12 Pro Max, pẹlu ẹgbẹrun lọna ọọdunrun naira ti wọn gba lọwọ fun ijọba.
 
Bakan naa ni Onidajọ Abdulgafar ju Ọmọgbọlahan sẹwọn oṣu mẹfa gbako, ati pe koun naa gbagbe mọto Hyundai Sonata, awon foonu ati kọmputa alegbeka, to fi mọ ẹgbẹrun lọna ọọdunrun naira ti wọn gba lọwọ fun ijọba Naijijria.
 
Ẹwọn oṣu mẹfa gbako naa ni ile ẹjọ ju Lambẹ ati Ọlọrunfẹmi si, ati pe awọn mejeeji naa gbọdọ gbagbe mọto Lexus ES 350, Toyota camry, iPhone 12 ati iPhone 13 ti wọn gba lọwọ wọn fun ijọba apapọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI