Ijọba Kwara ti bẹrẹ igbesẹ lati tọwọ bọwe adehun pẹlu ijọba Japan - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, June 22, 2023

Ijọba Kwara ti bẹrẹ igbesẹ lati tọwọ bọwe adehun pẹlu ijọba Japan


Latile mu itẹsiwaju ati idagbasoke ba eto-ẹkọ ati eto iṣẹ agbẹ ati ọgbin, pẹlu awọn nnkan miran ijọba Kwara labẹ Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti bẹrẹ igbesẹ tuntun lati tọwọ bọwe adehun pẹlu ijọba ilẹ Japan.

Ileeṣẹ kan lorileede Japan, eyi ti wọn pe ni Japan International Cooperation Agency (JICA) la gbọ pe awọn ati ijọba Kwara ti jọ n ṣepade lati tọwọ bọwe adehun pẹlu wọn laipẹ yii.

Laipẹ yii ni awọn aṣoju ajọ JICA ṣabẹwo si ipinlẹ Kwara lati wo ọna ti wọn yoo fi dide iranwọ fun wọn, lati le jọ ni ajọṣepọ ti yoo lọọrin, paapaa l'ẹka eto ẹkọ ati iṣẹ agbẹ ati ọgbin.
 
Ajọ naa ni iroyin fi to wa leti wọn n ṣiṣẹ pẹlu Ojọgbọn Raheem Adaramaja to jẹ alakoso eto ẹkọ nipinlẹ naa, iyẹn State Universal Basic Education Board.

Nibi ipade wọn, gomina ṣalaye pe awọn ti ṣiṣẹ takuntakun lori ọrọ eto ẹkọ nipinlẹ naa, nipa atunṣe ati atunkọ awọn ile-ẹkọ to ti dẹnukọlẹ.
 
O wa gboriyin fun ajọ JICA fun bi wọn ṣe nawọ ibaṣepọ to dan mọran wa si ipinlẹ naa, to si lawọn naa ṣetan lati tọwọ bọwe adehun pẹlu wọn.


No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI