Ṣọọbu ile itaja nla lawọn eleyii fẹran lati maa ja l'Ogun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, June 8, 2023

Ṣọọbu ile itaja nla lawọn eleyii fẹran lati maa ja l'Ogun


Ọrọ Yoruba to sọ pe 'ọjọ gbogbo ni ti ole, ọjọ kan ṣoṣo bayii ni ti olohun' lo ṣẹlẹ nigba ti ọwọ tẹ awọn ọrẹ mẹta ti wọn sọ pe wọn ko niṣẹ meji ju iṣẹ idigunjale n'ipinlẹ Ogun ati agbegbe rẹ lọ.
 
Tirela nla la gbọ pe wọn maa n gbe dani, bi wọn ba fẹẹ lọ digunjale, ati pe ṣọọbu itaja to tobi, iyẹn eyi ti wọn n pe ni Warehouse la gbọ pe wọn fẹran lati maa ja lole.
 
Bi wọn ba si ti gbe tirela nla ọhun debẹ, gbogbo ẹru to ba wa ninu ṣọọbu naa ni wọn yoo palẹmọ rẹ, ti wọn yoo si lọ ta a danu lowo pọọku.
 
Mọruf Yusuf to jẹ agbẹnusọ f'awọn ẹṣọ aabo ijọba ipinlẹ Ogun ti a mọ si So-Safe Corps to gbe iroyin naa si wa leti sọ pe nnkan bi aago mejila ku iṣẹju mẹẹdogun alẹ ọjọ Aiku tii ṣe Sannde to kọja yii ni awọn oṣiṣẹ wọn tẹle wọn lọ sibi ti wọn ti lọ jale laimọ.
 
Yusuf sọ pe itaja nla kan to pe ni Power Gas Company to wa lagbegbe Igere, opic Estate, Ado-Odo Ọta ni wọn lọ ko, ko to di pe aṣiri wọn tu, iyẹn lọjọ kẹrin, oṣu yii.
 
Gẹgẹ bo tun ṣe ṣalaye, o ni Amachi John, ẹni ogoji ọdun; Moses Lazarus, ẹni ọdun mọkanlelogoji ati Chidi Peter, toun jẹ ọmọ ọdun mẹtadinlọgbọon lorukọ awọn mẹtẹẹta, ati pe tirela akẹru ti nọmba idanimọ rẹ jẹ SMK334XD ni wọn gbe lọ.

O ni gbogbo awọn ẹru ti wọn fẹẹ ji ko patapata ni wọn ti gba lọwọ wọn, to fi mọ tirela naa. Bẹẹ lo fi kun un pe kii ṣe awọn mẹta yii nikan ni wọn lọ, o l'awọn yooku ti na papa bora, ṣugbọn ti iwadii lati rọwọ to wọn ṣi n lọ lọwọ.
 
O pari ọrọ rẹ pe ọga awọn Olusọji Ganzallo ti fa awọn afurasi ọdaran naa le awọn ọlọpaa ẹkun Agbara lọwọ fun iṣẹ iwadii kikun.
 
 
 

 
 
 

 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI