Tinubu yoo pari atunṣe ileeṣẹ ifọpo kan titi oṣu kejila - NNPC - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, June 1, 2023

Tinubu yoo pari atunṣe ileeṣẹ ifọpo kan titi oṣu kejila - NNPC


Gbogbo eto la gbọ pe o ti pari bayii fun Aarẹ Bọla Ahmẹd Tinubu lati bẹrẹ atunṣe ọkan lara awọn ileeṣẹ ifọpo mẹrin to ti dẹnukọlẹ lorileede Naijiria, ti yoo si bẹrẹ iṣẹ lakọtun ko too to oṣu kejila, ọdun 2023.
 
Alakoso ati alabojuto ileeṣẹ Nigerian National Petroleum Company Limited, NNPC, Mele Kyari lo sọrọ naa lonii, Ọjọbọ tii ṣe Tọsidee lakoko to ṣabẹwo si alaga ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC, Sẹnetọ Abdullahi Adamu ni olu ileeṣẹ ẹgbẹ naa to wa niluu Abuja.

Kyari sọ pe Aarẹ ti n ṣiṣẹ lati rii pe irora araalu dikun latari owo epo to lọ soke, eyi ti owo iranwọ ori epo t'ijọba apapọ yọ kuro.

Siwaju sii lo fi kun ọrọ rẹ pe ida mejidinlogoji epo ti wọn n pin kaakiri orileede Naijiria lo jẹ pe awọn ipinlẹ mẹrin pere lo n lọ, to si ni awọn ipinlẹ naa ni Ekoo, Abuja, Kano ati Rivers.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI