Oriire nla ni Tinubu jẹ fun iran Yoruba - Salvador - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, July 14, 2023

Oriire nla ni Tinubu jẹ fun iran Yoruba - Salvador


Alaga egbe oṣelu PDP tẹlẹ n'ipinlẹ Ekoo, Oloye Salvador ti sọ pe ki gbogbo ọmọ Naijiria gbaruku ti Aarẹ Bọla Ahmẹd Tinubu, nitori pe oriire nla lo jẹ fun wọn.

Salvador lo sọrọ naa lasiko to n gba ikọ awọn akọṣẹmọṣẹ iroyin Yoruba, League of Yoruba Media Practitioners, lalejo laipẹ yii.

Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe:

Lati ọjọ ti wọn ti da Naijiria silẹ, Lati 1960, taa ti gba ominira, akọkọ ti emi maa ri ọmọ Yoruba to jẹ aarẹ, emi o le pe Baba Shonẹkan ni aarẹ,nitori fidihẹ ni, ko ni agbara kankan, ko si nnkan to le da ṣe, wọn ko to ija wa gbe.

Bi ẹ ba ri ẹni to to ija wa gbe, emi ati Tinubu, a saa si ninu ẹgbẹ kan naa,amọ ti ẹ ba n sọ ẹni to to o gbe awọn ni, iya ọjọ iwaju, o le ba wa kọ ọ,ẹnikan bi i lere nigba ti wọn ṣe iplongo idibo pe awọn eto w ni ẹ ni lọwọ, ti ẹ fẹẹ gbe kalẹ, o sọ pe mi o le sọ o, ti mo ba lọ sọ, ki wọn lọ pa mi.

Idi ree, kudiẹkudiẹ ti baba wa Awolọwọ ṣe, eyi Oloye MKO Abiọla ṣe, oun ko le ṣe e, itumọ ẹ niyẹn, kin ni kudiẹkudiẹ ọhun,wọn lọ leri, wọn lo leka, pe bawọn ba dori aga,awọn a ṣe awọn nnkan bayii,awọn to ba maa ni lara, ko nii jẹ ki ẹ de bẹ.

Lakooko yii, o ṣẹnu ẹ dakẹ, inu igbo ni ẹyẹ n gbe, o gbe ẹnu ẹ dakẹ, o jẹ ki agbara tẹ oun lọwọ, o waa bẹrẹ iṣẹ ọhun,ẹ o rii pelaaarin ọsẹ kan to de bẹ, gbogbo ọna ole, jibiti tawọn tibi n ṣe, o kọkọ muu kuro, o maa nira, ko si nnkan to dara ti ki i nira, lati ọjọ ti wọn ti da ilẹ Yoruba silẹ, ti wọn ti da Naijiria silẹ, ọmọ ilẹ Yoruba kankan ko jẹ ọga agba patapata fun aṣobode ri. Ko pe ọjọ mẹta to debẹ lo yii pada, ẹ woo, bi wọn ṣe fawọn onibode sapo lati ọdun yii, ko pe ọjọ mẹta, oun naa wa ṣe pe nnkan ti ẹ ṣe fun wa loun naa yoo da pada.

Yoruba lo wa n ko si gbogbo ẹ, ẹ ẹ ri pe ka to wi, ka to jokoo, o ti yọ ọga banki agba, o ti fi ọmọ kaarọ o-jiire si. Ati bẹẹbẹẹ lọ. Ẹ ma reti tọrọ, ẹ ma reti kọbọ, ẹ ranti awọn ọmọ yin lọjọ iwaju.Ti ẹ ba ri ẹni to n ṣe eleyii, ẹ gbaruku ti, nitori nnkan to n ṣe fun awọn ọmọ yin lọjọ iwaju ni o.

Bi a ba wa ri bayii onikaluku wa lo maa ni ipa to maa ko, fun ilọsiwaju ilẹ Yoruba, ki ẹ ma jẹ ki ipa yin ko gbẹyin o.

Ọbasanjọ ko ni ẹkùn tabi agbegbe , ẹni to ni, to ti n ja ijagbara fun ilẹ Yoruba, oun ni Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu, akọkọ ni, to yanranti.

Awọn ko ṣe jẹ ki MKO Abiọla jẹ, ti wọn wa lọ mu eeyan wa lati inu tubu,, ẹni ti wọn lọ mu wa, wọn ti ni adehun pẹlu ẹ. Gbogbo nnkan tawọn ara oke ọya ba n fẹ, ni yoo maa ṣe,ki i ṣe nnkan ti awa ba n fẹ, nitori ẹ ni ẹ ṣe n ri ti,Baba wa Ọbasanjọ, ṣe n sọ lọjọ naa pe ko yan ipo si gbogbo ipinlẹ, awa lo tun fiya jẹ ninu ẹ.

Gbogbo ipo awọn ara oke ọya lo n fun, wọn ko ni agbara, wọn kan jẹ aarẹ ni. Nitori awọn ara oke ọya ni wọn fi sibẹ.

Ẹ fi ẹgbẹ oṣelu silẹ, bi a ba sọ fun yin pe ẹgun gun yin ni ẹsẹ, ọ lọ ki ẹ yọ,, ko ma ba ta yin, to ba ta yin, a tori si yin lara, a si ṣe yin leṣe,ewo ni ti ẹgbẹ oṣelu ninu ọrọ ilọsiwaju ilu.Kin ni ẹ fẹẹ fi wọn ṣe, emi ko jisoro ẹgbẹ oṣelu kankan,igbesẹ lasan ni lati fi de ibikibi ti ẹ fẹẹ de.

Awọn agba bọ wọn ni, agba ki i wa lọja ki ori ọmọ tuntun wọ, ori ọmọ tuntun kọ lo wa fẹẹ wọ yii, ori awọn agba gan-an ni, a maa mura lati ba ara wa sọ ootọ ọrọ,ọmọ ẹni ki i ṣe idi bẹbẹrẹ ki a fi ilẹkẹ sidii ọmọ ẹlomii-in.

Oun lo mu Baba Faṣoranti ṣe nnkan to n ṣe, Baba Adebanjọ oun sọ  pe oun ba Tinubu ja, o ni a fi ti wọn ba ṣe atunto, ṣebi oun naa ni wọn n ṣe yii. Gbogbo wa la jọ wa ipade apero ni 2014, emi naa wa nibẹ, gbogbo nnkan taa to pe ti wọn ba ṣe ilu yii a di rẹpẹtẹ, oun ni wọn n ṣe yii.

Adura ni ki ẹ maa fi ran Aarẹ yin tuntun yii lọwọ, nitori bawọn ara oke ọya ko ba pa a, wọn yoo dero ẹyin patapata, nitori bo ṣe n ba lọ yii, ọrọ atunto yii lo tun ti gbe siwaju wọn yii, boya ẹ ti ri gbọ, ahesọ ọrọ to n jade, bi ẹ ba si pe bẹẹ ẹ o ri ootọ, gbogbo ipinlẹ to wa ni ẹkun mẹfẹẹfa lorileede yiim ki ọkọọkan wọn ni ipinlẹ meje, ki aparo kan ma le ga ju ọkan lọ.

Wọn tun ti la silẹ pe, bi a ba pin ni ipinlẹ meje,meje,ipinlẹ kọọkọn gbọdọ maa pa biliọnu dọla, eyi ti ko ba ti le pa to bẹẹ, wọn yoo kede ẹ bi ipinlẹ pajawiri, ẹ sẹsẹ fẹẹ mura, k onikaluku lọ ṣe alumọni ti Ọlọrun fi kẹ wọn, ki wọn maa jokoo ti owo baba.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI