Ẹgbẹ awọn olukọ gbe oriyin f'AbdulRazaq, wọn l'awọn yoo tubọ maa fi ara si iṣẹ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, July 26, 2023

Ẹgbẹ awọn olukọ gbe oriyin f'AbdulRazaq, wọn l'awọn yoo tubọ maa fi ara si iṣẹ


Ẹgbẹ awọn olukọ to wa labẹ aburada Nigerian Union of Teachers (NUT), ẹka ti ipinlẹ Kwara ti gbe oriyin nla fun Gomina AbdulRahman AbdulRazaq lori ọna to gba ṣe eto igbega ọdun 2019/2020.

Ninu atẹjade ti alaga ẹgbẹ awọn olukọ naa to n palẹmọ lati lọ, Kọmureedi Bashir Oyewọ gbe jade laipẹ yii, o ni iṣẹ takuntakun ni Gomina AbdulRazaq n ṣe, paapaa lẹka eto ẹkọ.

Kọmureedi Oyewọ ni iṣẹ takuntakun ti alaga f'ẹgbẹ TESCOM, Alaaji Abubakar Bello Taoheed n ṣe lati rii pe idagbasoke de ba igbayegbadun awọn oṣiṣẹ mu koriya wa.

O wa lo anfaani naa lati dupẹ gidigidi lọwọ gomina wọn, pẹlu ileri wi pe awọn yoo tubọ maa tẹpa mọ iṣẹ wọn loorekoore.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI