Sẹnetọ Yayi lo kaju oṣuwọn fun ipo gomina ipinlẹ Ogun l’ọdun 2027 – Alaaji Azeez Ibrahim - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, July 27, 2023

Sẹnetọ Yayi lo kaju oṣuwọn fun ipo gomina ipinlẹ Ogun l’ọdun 2027 – Alaaji Azeez Ibrahim


Ọkan pataki lara awọn alẹnulọrọ ninu ẹgbẹ ọmọlẹyin Yayi, Alaaji Azeez Ayọmikun Ibrahim ti sọ pe ko si ẹni ti ipo gomina ipinlẹ Ogun tun tọ si lọdun 2027, to kọja Sẹnetọ to n ṣoju ẹkun Yewa nile igbimọ aṣofin agba orileede Naijiria, Sẹnetọ Ọlamilekan Adeọla ti ọpọ awọn eeyan tun mọ si Yayi.

Alaaji Azeez Ayọmikun Ibrahim lo sọrọ naa laipẹ yii niluu Abẹokuta lakoko to n ba awọn ọmọlẹyin Yayi sọrọ nibi ipade wọn, to si ni ki onikaluku lọ maa gbaradi fun oṣelu 2027, lati ri i pe ipo naa ja mọ wọn lọwọ.

O ni ẹdun ọkan lo maa n jẹ f’oun wi pe latigba ti wọn ti da ipinlẹ naa silẹ, ọmọ Yewa ko ti i di gomina ri, to si ni asiko naa ti to fun wọn bayii, nitori pe awọn ti lẹni to kaju oṣuwọn.

Siwaju sii ni ọkunrin naa jẹ ko di mimọ pe ko si nnkan meji to fa idi ti ọmọ Yewa ko ṣe ti i di gomina latari gbogbo ilakaka wọn, bi ko ṣe pe awọn ko ti i ni aṣoju rere t’awọn araalu nifẹ si.

O ni pataki idi naa lo tun sọ pe aigbọra-ẹni ye to n ṣẹlẹ laaarin awọn Yewa, to fa a ti oludije rẹpẹtẹ fi n jade lakoko kan naa, ṣugbọn to sọ pe awọn ti wa ni iṣọkan bayii lati ri i pe awọn parapọ.

“Bi ẹ ba wo o daadaa, latigba ti wọn ti da ipinlẹ Ogun silẹ, ko ti i si ọmọ Yewa to di ipo gomina mu. Ki lo fa a, idi ni pe ẹnu wa ko ko, a ko fi imọ ṣọkan lori ẹni ti a maa fa ale. Idi rẹ ree ti ọpọ eeyan fi n jade lati ẹkun Yewa.

“Ipo kan ṣoṣo la n du, bi a ba fẹ ki ipo yii ja mọ wa lọwọ, a fi ka f’imọ ṣọkan lati fa ẹnikan ṣoṣo kalẹ. Inu mi si dun bayii wi pe a ti ri ẹnikan ṣoṣo to kaju oṣuwọn, Sẹnetọ Yayi si ni.

“Awọn eeyan le maa sọ oriṣiriṣi, ṣugbọn awọn ti oye ko ye lo n sọ isọkusọ, nitori pe ẹni ti araalu n fẹ jakejado ni Yayi. Oun si la fẹẹ lo gẹgẹ bi i gomina.

“Bi ẹ ba wo ọdun ti Yayi ti n di ipo oṣelu mu bọ, ẹ maa ri i pe o ni ọgbọn, imọ ati oye lati tukọ ipinlẹ Ogun ju ẹnikẹni to le jade lọdun 2027 lọ.

“Ẹnu awa Yewa ti ko bayii lati fọwọsowọpọ pẹlu ẹ, to si da mi loju pe ko le ni alatako kankan. Ẹni to ba wo o pe oun fẹẹ f’igagbaga pẹlu Yayi lọdun 2027, iyẹn lati Yewa nibi, ẹni naa kan fẹẹ fi owo rẹ jona lasan ni, nitori pe ko saaye mọ.”

Bakan naa lo gba awọn ọmọ orileede Naijiria lamọran lati ṣe ọpọlọpọ suuru fun Aṣiwaju Bọla Ahmẹd Tinubu lakoko ọwọngogo to wa nita lasiko yii, to si loun nigbagbọ pe nnkan yoo dẹrun f’awọn araalu laipẹ.

O ni lati maa nigbagbọ ninu ọrọ t’awọn agbaagba maa n sọ pe ‘ohun to le koko ṣi n bọ wa dẹrun’.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI