Gbajumọ puromota, Ajiki-Olu ṣabẹwo si Olu Ibeṣe tuntun, ni Kabiyesi ba sọ ọjọ ti inu rẹ dun ju laye - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, July 27, 2023

Gbajumọ puromota, Ajiki-Olu ṣabẹwo si Olu Ibeṣe tuntun, ni Kabiyesi ba sọ ọjọ ti inu rẹ dun ju laye


Ọjọ manigbagbe l’ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii jẹ ninu itan, lori bi gbajugbaja puromota olorin nni, Oloye Arẹmu Bamgboye ti ọpọ awọn eeyan mọ si Ajiki-Olu ṣe ṣabẹwo si Ọba tuntun ti ijọba ipinlẹ Ogun buwọ lu fun ilu Ibeṣe lọdun to kọja, Ọba Oluwarotimi Oluwaṣeyi Mulero.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, ọjọ naa lo pe ọdun kan gbako ti ijọba ipinlẹ Ogun f’ontẹ lu Ọba Mulero gẹgẹ bi Aboro tiluu Ibeṣe to wa n’ijọba ibilẹ Yewa South, ipinlẹ naa.

Ajiki-Olu, nigba to n sọrọ jẹ ko di mimọ pe wi pe oun ti n gbọ nipa ipo ọba ilu Ibeṣe to ti ṣi silẹ tipẹ, ati pe oun gbọ nipa bi eto jijẹ ọba ọhun ṣe n lọ nigba naa, bo tilẹ jẹ pe oun ko fi ọkan si awọn to n du ipo naa.

Gbajumọ puromota olorin naa, to tun jẹ alaṣẹ ati oludasilẹ ileeṣẹ Gboin-Gboin, egboogi am’arata kebe naa sọ pe laipẹ yii loun gbọ nipa ẹni ti ijọba ipinlẹ Ogun f’ontẹ lu, to si jẹ iyalẹnu wi pe ẹni toun ti mọ tipẹ ni.

O ni ọrẹ timọtimọ loun ati Ọba Mulero lati ọdun to ti pẹ sẹyin, ati pe ajọṣepọ to lọọrin wa laarin wọn, ṣugbọn toun ko mọ pe ọrẹ oun ti di ọba.

Ajiki-Olu ni oun ko le ṣai ma wa ki kabiyesi, nigba toun ti gbọ iroyin naa, lati ba a yọ, koun si tun fi atilẹyin han si i, gẹgẹ b’awọn ti n ṣe latẹyin wa.

Ọkunrin naa to tun jẹ ọkan lara awọn agba oloye niluu Ijẹja, Abẹokuta sọ pe oun ṣetan lati gbaruku ti Ọba Mulero, ati pe gbogbo eto tabi ayẹyẹ ti yoo ba waye loun yoo maa lọ lati ba wọn ṣe e, fun idagbasoke ilu Ibeṣe.

Bakan naa lo pe rọ gbogbo awọn ọmọ ilu Ibeṣe ti wọn wa loke okun lati ma ṣe gbagbe ile, bẹẹ lo ni ki wọn dide ifọwọsowọpọ pẹlu ọba wọn, fun ilọsiwaju, ati lati jẹ ki orukọ ilu naa wa ninu iwe akọsilẹ agbaye.

Lakotan, Ajiki-Olu gbadura ẹmi gigun ati alaafia fun Ọba Mulero.

Nigba toun naa n fi idunnu rẹ han, Ọba Oluwarotimi Oluwaṣeyi Mulero sọ pe idunnu nla lo jẹ foun lati gbalejo agba puromota naa, nitori pe o pẹ t’awọn ti f’oju kan ara wọn gbẹyin.

Kabiyesi jẹri si i wi pe ajọṣepọ gidi wa laaarin awọn tẹlẹ, nitori t’awọn jọ bẹrẹ lati kekere ni, to si loun dupẹ bi Ajiki-Olu ṣe pọn oun le lati ṣabẹwo s’oun.

Ọba Mulero sọ pe ọjọ naa, iyẹn ọjọ karundinlọgbọn, oṣu keje, ọdun 2022 ni inu oun dun ju laye, nitori pe ọjọ naa ni gomina ipinlẹ Ogun, Ọmọọba Dapọ Abiọdun f’ontẹ lu oun gẹgẹ bi Aboro tiluu Ibeṣe, toun si gba iwe ẹri.

Kabiyesi ni ọjọ to tun pe ọdun kan gbako, ni Ajiki-Olu tun wa ṣabẹwo s’oun lati fi ifẹ han. O ni ohun to daju bayii ni pe ọjọ naa, apẹẹrẹ rere lo jẹ, nitori pe ni gbogbo igba lo n fi itan tuntun balẹ f’oun.

O wa gbadura fun ilọsiwaju fun Ajiki-Olu, to si loun naa yoo tẹsiwaju lati maa na ọwọ ifẹ si i titi lai.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI