Orile-Ilawọ: Gomina Abiọdun ko lẹtọọ lati yan ọba fun wa, bi ẹ ba ri ẹnikẹni, ẹ lu wọn bolẹ - Ogunsanya, oludije si ipo ọba to padanu - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, July 30, 2023

Orile-Ilawọ: Gomina Abiọdun ko lẹtọọ lati yan ọba fun wa, bi ẹ ba ri ẹnikẹni, ẹ lu wọn bolẹ - Ogunsanya, oludije si ipo ọba to padanu


Bi ijọba ipinlẹ Ogun labẹ Gomina Dapọ Abiọdun ko ba tete wa nnkan ṣe sọrọ Ọgbẹni Lawrence Ogunsanya, ọkan lara awọn oludije s'ipo ọba niluu Orile-Ilawọ, ṣugbọn to ti padanu tipẹ, ẹni to n fojoojumọ ko tọọgi kaakiri lati maa lodi si ojulowo ọba to ti jẹ, a jẹ pe gomina ko nifẹẹ awọn araalu to n ṣe ijọba le lori, paapaa awọn araalu Orile-Ilawọ to wa n'ijọba ibilẹ Ọdẹda.
 
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, latigba ti ijọba ipinlẹ Ogun ti kede Ọba Oluṣẹgun Alexander Oluṣẹgun Macgregor gẹgẹ bi Olu Orile-Ilawo ni wọn sọ pe Ogunsanya ti n ko tọọgi kaakiri lati maa dunkooko mọ ọba naa, to si n ni k'awọn araalu ma ṣe gba laaye.

Koda, bi Ọba Adedapọ tẹjuoṣo to jẹ Ọṣilẹ Oke-Ọna Ẹgba naa ko ba tete dide si ọrọ yii, Orile-Ilawọ to wa labẹ Oke-Ọna Ẹgba ko nii ni isinmi, afaimọ si ni k'awọn araalu ma dide ogun si ara wọn.
 
Ninu awọn fọnran kan to tẹ wa lọwọ lọsẹ to kọja yii la ti ri Ogunsanya nibi to ti n sọ f'awọn araalu Orile-Ilawọ lati ma ṣe gba Ọba Macgregor laaye niluu naa, to si ni wọn ko gbọdọ fọwọsowọpọ pẹlu ẹ.
 
Ogunsanya sọ pe oun nikan ni ipo ọba tọ si gẹgẹ Olu Orile-Ilawọ, ṣugbọn ti Gomina Dapọ Abiọdun fi oṣelu gbe e fun Macgregor, ẹni to pe ni atọhunrinwa.

Ninu fọnran naa, Ogunsanya jẹ ko di mimọ pe bi wọn ba ri iranṣẹ Ọba Macgregor, wọn ko gbọdọ gba a laaye lati jiṣẹ kankan, nitori pe gbogbo erongba wọn ni lati ta ilẹ ilu f'awọn ajoji, to si ni gomina ko laṣẹ labẹ ofin lati yan ọba fun wọn, ati pe oun ti gbe wọn lọ si kootu lori ẹ.
 
"Macgregor kii ṣe ọba yin o, ọba kangaru lo jẹ. Emi ni mo duro siwaju yin, ti mo n sọrọ yii. Ẹ ya fidio mi, ki ẹ si lọ fi han an, nitori pe mi o sọrọ ẹyin, boun gan ba duro nibi, maa yẹyẹ ẹ. Gomina gan-an to fi jẹ ọba, ofin ko sọ pe ko fi jẹ. Emi yii n ba gomina po wahala ni gbogbo igba

"A ti wa ni kootu, ẹ ma jẹ ki ẹnikankan da yin laamu. Gbogbo ẹyin ti ẹ ba n gbọ ọrọ rẹ kan n fa ọwọ aago sẹyin  ni, nitori pe ẹ ko ni jẹ ka ri ipinnu wa ṣe. Mo mọ pe ẹni to ba jẹ ọmọ-ọkọ Ilawọ ko nii tẹlẹ Macgregor, nitori pe a ko mọ ọn ri.

"Ki i ṣe ọdọ wa nikan ni ẹru ti n jẹ Balogun, ọba, bo ṣe ri kaakiri niyẹn. Macgregor ko ni ẹnikankan to fẹẹ fi jẹ Baalẹ, ẹyin ti ẹ ti jẹ Baalẹ tẹlẹ, ẹ maa lo ipo yin lọ. Bi ẹnikẹni ba ti ba a yin fa a, ẹ pe mi, loju ẹsẹ ni maa debẹ.

"Ẹ ma fun wa laaye rara, nitori pe bi wọn ṣe fa a gba ilẹ yin ni wọn n ṣe. Nigba to ba ya, awa funra wa la ma maa ṣe ijọba wa to ba ya ni abule yii, nitori pe ti ilu ko ba ti gba nnkan ti a n sọ, a maa kuro labẹ ilu. Idi ti a ṣi ṣe wa labẹ Ilawọ ni pe a ko tii fẹ ba a jẹ bayii. Ko si nnkan ti a ko le ṣe niluu wa yii.

"Ni bi mo ṣe n sọrọ yii, Macgregor kii ṣe ọba wa ni Orile-Ilawọ, a wa ni kootu, ko ni agbara kankan lati p'aṣẹ. Ti ẹ ba ti ṣe ilodi si, to ba wa fi ọlọpaa ko o yin, bi ẹ ba sun teṣan, ẹ sọ pe ọmọ ale ni mi, nitori pe maa gba yin silẹ.
 
"Ẹ ba ẹnikẹni fa wahala wi pe ẹ ko ti i ni ọba, ẹ le wọn pa wi pe wọn ko gbọdọ wa ṣe ohunkohun nibi. Ẹ da wahala naa si wa lọrun, a maa dide sii yin."

Ogunjọ, oṣu keje, ọdun yii la gbọ pe awọn tọọgi kan ti wọnn jẹ ọmọ ẹyin Ogunsanya lọ kọlu Muyideen Ọmọtọshọ lori wi pe o n ṣagbatẹru Ọba Macgregor, to si ku diẹ ki wọn pa. Awọn to fi iṣẹlẹ naa to wa leti sọ pe niṣe ni Muyideen ṣebi ẹni to ti ku, ko to di pe wọn fi silẹ lọ.
 
Awọn ara agbegbe naa ni wọn sare gbe e lọ si ọsibitu, nibi to ti n gba itọju lọwọ.
 
Ninu ọrọ rẹ, Kabiyesi, Ọba Macgregor rawọ ẹbẹ s'ijọba ipinlẹ Ogun lati dide iranlọwọ fun eto aabo to pe ye niluu Orile-Ilawọ ati agbegbe rẹ, ati pe ki ijọba tete da Ogunsanya lọwọ kọ lori bo ṣe n fojoojumọ da wahala silẹ laaarin ilu.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI