Ifọwọsowọpọ lo ṣe pataki fun idagbasoke - Ijọba Kwara - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, July 19, 2023

Ifọwọsowọpọ lo ṣe pataki fun idagbasoke - Ijọba Kwara


Ijọba ipinlẹ Kwara ti gba awọn ajọ Civil Society Organizations (CSO) ati Community Base Organizations (CBO) lati fọwọsowọpọ ṣiṣẹ papọ nitori pe ifọwọsowọpọ lo ṣe papaki.

Gomina AbdulRahman AbdulRazaq lo gba awọn ajọ naa lamọran laipẹ yii, to si ni ki wọn ṣiṣẹ papọ pẹlu ijọba ipinlẹ naa lati le ṣe aṣeyọri kan naa.

Nigba to n gba ẹnu gomina sọrọ nibi aṣekagba eto ti wọn pe ni Action Aid’s Local Rights Program (LRP), eyi to waye niluu Ilọrin, igbakeji gomina, Kayọde Alabi sọ pe bi awọn mejeeji ba le ṣiṣẹ papọ, wọn yoo jọ ni aṣeyọri kan naa fun ilọsiwaju ati idagbasoke ipinlẹ Kwara.

Nibẹ lo ti jẹ ko di mimọ pe ijọba ko ni gbogbo awọn amuyẹ lati yanju gbogbo ipenija to ba n koju ipinlẹ naa lakoko kan naa, fun idi eyi, o ni ifọwọsowọpọ pẹlu awọn ajọ ati ẹgbẹ lo maa n mu aṣeyọri wa.

Bakan naa lo sọ pe ijọba n ṣiṣẹ takuntakun lati rii pe ohun ti wọn fun awọn araalu ni wọn n fẹ, eyi to sọ pe o jẹ ọna lati gbogun ti iṣẹ ati oṣi, paapaa julọ lati gbogun ti aidagbasoke.
 


No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI