Nitori ẹsun jibiti to fi kan Saraki, akọwe PDP f'ẹgbẹ silẹ ni Kwara - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, July 19, 2023

Nitori ẹsun jibiti to fi kan Saraki, akọwe PDP f'ẹgbẹ silẹ ni Kwara


Akọwe ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP ni wọọdu Badari, ijọba ibilẹ Ilorin West, Malaamu AbdulRazaq Lawal ti kọwe fi ipo rẹ silẹ gẹgẹ bi ọmọ ẹgbẹ.
 
Malaamu Lawal lo sọ pe oun ko le maa tẹsiwaju mọ ninu ẹgbẹ PDP nitori awọn idi pataki kan to ye oun.
 
AWIKONKO gbọ pe ko si nnkan meji to fa a, bi ko ṣe awọn ẹsun ti ọkunrin naa fi kan Aarẹ ile igbimọ aṣofin agba orileede Naijiria tẹlẹ, Ọmọwe Bukọla Saraki wi pe o kowo ẹgbẹ jẹ.
 
Wọn ni ọkunrin naa sọ pe Saraki ko le ṣe akọsilẹ bo ṣe na owo ẹgbẹ ninu eto idibo apapọ to waye kọja lọ.



No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI