Opin de ba JAPA, Kwara gba awọn dọkita, nọọsi tuntun s'awọn ọsibitu ijọba - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, August 27, 2023

Opin de ba JAPA, Kwara gba awọn dọkita, nọọsi tuntun s'awọn ọsibitu ijọba


Ijọba ipinlẹ Kwara labẹ iṣakoso Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti gba awọn akọṣẹmọṣẹ oniṣegun oyinbo tuntun, iyẹn dọkita ai nọọsi s'awọn ọsibitu ijọba kaakiri ipinlẹ naa.
 
Ọjọbọ tii ṣe Tọsidee to kọja yii ni igbimọ alakoso awọn ọsibitu kaakiri ipinlẹ naa, Hospital Management Board (KW-HMB) bẹrẹ sii pin awọn dọkita ati nọọsi tuntun naa s'awọn ọsibitu ti aaye wọn ti ṣofo silẹ tipẹ.
 
Gomina AbdulRazaq ti paṣẹ pe ki igbimọ KW-HMB bẹrẹ sii fi awọn oṣiṣẹ tuntun naa s'awọn eeyan to ti ṣofo, yala nipa awọn to ti fẹyinti, tabi awọn to ti fi iṣẹ silẹ.

Lara awọn ẹka ti wọn gba naa la ti ri awọn dọkita, nọọsi ati awọn onimọ nipa oogun ti a mọ si pharmacists.

Nigba to n sọrọ, Zubair Abdulhafeez to jẹ Service Improvement Officer, KW-HMB, ṣalaye pe awọn oṣiṣẹ tuntun naa ti la idanilẹkọọ kọja, ati pe ajọ SERVICOM lo ṣe idanilẹkọọ ọhun fun lati mọ bi iṣẹ wọn yoo ṣe maa lọ loore-koore.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI