Idi ti nko fi kuro ni Naijiria lẹyin ti Tinubu jawe olubori ninu eto idibo ọdun 2023 – Bọde George - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, October 29, 2023

Idi ti nko fi kuro ni Naijiria lẹyin ti Tinubu jawe olubori ninu eto idibo ọdun 2023 – Bọde George


Oju to ri Eégún, to ri Orò to si tun ri Gẹ̀lẹ̀dẹ́ ti dopin iran wiwo lawọn agba wi.  Eeyan to ti figba kan ṣe ṣọja to tun depo gomina nibẹ ko kere ninu aye o. Ka too tun wa sọ pe o ṣe Alaga ileeṣẹ ọlọkọ ofurufu orilẹ-ede yii, o tun depo igbakeji alaga ninu ẹgbẹ PDP lapaa Guusu, o si pada di igbakeji alaga apapọ pẹlu. 

 

Oloye Ọlabọde Ibiyinka George la n ba wi, ọmọ bibi ipinlẹ Eko ni. Ani Baba agba ninu oṣelu Naijiria to loun yoo filu yii silẹ bi Tinubu ba di aarẹ la n sọrọ ẹ. Baba naa ṣalaye lori ọrọ ọhun ati bi Naijiria ṣe n bajẹ si i lasiko yii, o sọ oju abẹ nikoo fun ikọ akọroyin ledeeYoruba, League Of Yoruba Media Practitioners to gba lalejo nile rẹ n’Ikoyi lọjọ Iṣẹgun to kọja, eyi lohun ti Oloye Bọde George sọ:

 

 

Bi wọn ṣe n ji awọn ọba alaye gbe lasiko yii jẹ ohun to n ya awọn eeyan lẹnu, ki lẹ ro pe o fa a?

 

Naijiria asiko yii, a ko fẹran ara wa. Nnkan buruku meji kan n ba wa ja ta a dẹ fi n tanra wa jẹ, awọn nnkan naa ni ẹlẹyamẹya ati ẹ̀sìn. 

 

Inu kalulu lo yẹ k’ẹsin ẹ wa, ohun to ba wu kaluku lati ṣe lo yẹ ko gbagbọ. Ohun tẹsin kuku n kọ wa naa ni pe ka ma ṣeka fọmọlakeji, ohun tiwọ ko ba ni i gba, ma ṣe e fọmọ ẹlomi-in, ko ju bẹẹ lọ.

 

Ẹsin mẹta naa to wa lorilẹ-ede yii ni Kristẹni, Islam ati tawọn Alajọbi, yee-pa-ripa. Emi o wa ri idile kan ti ko ni mẹtẹẹta. Ki la wa n bara wa ja si ta a n fi tiwa ni ẹlomi-in lara. B’Ọlọrun ṣe da iwọ naa lo da awọn ẹlomi-in. Nile tiwa, ẹgbọn mi ti mo tẹle, obinrin ni, Musulumi lo fẹ, Alaaja lẹgbọn mi. Ṣe mo maa waa gbe e ju sabẹ mọto pe mi o fẹẹ ri i ni, ẹgbọn mi ṣi ni.

 

Mo ni aburo to fẹ Musulumi, to jẹ pe Musulumi naa ti di pastọ leni, ki waa ni lalakokofẹfẹ, ki la n le, ki la n wa ta a fi n tanra wa jẹ, ta o gba funra wa.

 

Ẹ jẹ jẹ ka ṣe e ire to ri ọjọ atisun, ko kuku sẹni to waye ti ko ni i pada. Ẹ jẹ ka ṣe e ire ki wọn le ri adiẹ irana sin wa lọjọ ta a ba lọ.

 

Ẹtan la n ba ka ni Naijiria, a o ti i sọ otitọ ọrọ funra wa. Ṣe ẹ ri iwe ofin ta a n lo ni Naijiria, Baba nla abosi ni, a n tanra wa jẹ ni. Ta a ba lọọ gbe iwe ofin yẹn ka tun un yẹwo, ka ṣe e bi wọn ṣe n ṣe e ko le ri bo ṣe yẹ ko ri, ba a ṣe maa maa lọ bi igba teeyan wa ti ko lọpọlọ niyẹn, iranu ni.

 

Koda, Amẹrika paapaa ta a ni a n lo iru ofin wọn, awọn funra wọn fun awọn ipinlẹ lagbara lori awọn nnkan amuṣọrọ to wa niluu wọn.

 

Iyẹn ni wọn fi n sọ ilu dẹrọ, ṣugbọn awa nibi, iwe ofin ta a lo nisinyi, o da bii tawọn ologun ni, ṣebi iṣẹ ologun lemi ṣe.

 

Ọga kan lo maa wa loke, nnkan to ba dẹ sọ labẹ ge. Abosi la n ṣe lasiko yii ta a n sọ pe Presidential kinni kan ni, a n tanra wa jẹ bi Iya Jimọ ni.

 

Ki lo kan wọn pẹlu ijọba ibilẹ mi nibi yii, ṣe wọn le mọ Iya Ọṣọ ju Ọṣọ lọ ni. Agbara ti wọn ko lọ s’Abuja yii, ti wọn gbe fun Olori oko nibẹ ti pọju.

 

Ko si ipinlẹ t’Ọlọrun ko fun ni nnkan ọrọ tiẹ, a wa ko gbogbo ẹ o di Abuja, eeyan kan aa wa jokoo ti i, o ti pọju.

 

Ok, ẹ ẹ ri i pe nigba ti Tinubu n yan awọn ọmọ Yoruba sipo agbara, awọn kan n binu pe Yoruba nikan lo n fi sibẹ. Nigba ti Buhari wa nibẹ, ki lo ṣe. Ọjọ teeyan mi-in ba tun debẹ, oun naa aa tun ṣe bẹẹ, ṣe bi ilu ṣe maa lọ siwaju niyẹn?

 

Lati 1998 ni mo ti bẹrẹ oṣelu, mo dẹ tun ṣiṣẹ ologun titi ti mo fi fẹyinti, ṣugbọn mo wo o pe iwe ofin ta a n lo yii, ki ni anfaani oṣelu teeyan loun fẹẹ ṣe fawọn eeyan ẹ, a n yiwee, ẹni ti nnkan ko tọ si, wọn aa gbe e fun un, gbogbo iyẹn la n ba kiri latijọ yii.

 

Nigba ti Buhari de to ni oun maa tun un ṣe, oun maa ra maṣinni tuntun fun eto idibo, inu wa dun. Lọjọ naa, a ṣe pati ninu ile mi nibi, nitori a gbagbọ pe o ti di pe ẹni taraalu ba fẹ lo maa depo niyẹn.

 

Ṣugbọn ki la ri, ẹtan. O ni maṣinni tuntun ti wọn fowo iyebiye ra ko ṣiṣẹ lọjọ to yẹ ko ṣiṣẹ. Ẹ wa tun lọọ n fọwọ kọ ọ, ta a lẹ n tan. Gbogbo abosi jatijati ta n bara wa ṣe , ko sọna nibẹ.

 

Emi naa ti fẹẹ pe eeti nisinyi( 80 years) ki ni mo tun n wa ju ki n maa sọ otitọ lọ fawọn ọmọ.

 

 A dẹ ti tun kinni yii wo nigba ti Jonathan wa lori aleefa o, nigba ti wọn gbe fun Buhari pe oun ree, wa bo o ṣe maa ṣe, niṣe lo ni ki wọn lọọ gbe e pamọ, ṣe eyi ta a n ṣe lọ yii lo wa daa, a n tanra wa jẹ ni. Ko loju, ko dẹ le lọna, irọ ti pọju.

 

Ẹ ni ko lọọ gbewe yẹn jade, Buhari to lọọ gbe e pamọ ti pada siluu nisinyi, ṣe ilu toro nisinyi, eni ti ko sunmọ mi bawo lo ṣe fẹẹ mọ ohun to n jẹ mi niya niluu mi.

 

Koko ni pe ki wọn din agbara ti wọn gbe fun wọn loke ku, ki wọn tun un to, ki wọn tun un pin la fi le lọ siwaju.

 

 Nigba tawọn Geesi de ti wọn lẹ wa pọ, wọn o wo ti boya ìṣe wa ati iwa wa dọgba. Bẹẹ la dẹ ṣe n ba a lọ, nibo la ba a de bayii, gbogbo iranu ta a ṣe.

 

NPC (Nothern People Council) Action Group ilẹ tiwa nibi, NCNC ni tawọn Ibo. O wa di pe awọn ẹya to pọju ni wọn maa n ni awọn eeyan nijọba, awọn ti wọn o pọ nkọ, ki lẹ maa ṣe fun wọn, wọn o lẹnu ọrọ, bi wọn ba tiẹ sọrọ wọn aa ho le wọn lori ni, iyẹn la ba lọ titi togun fi de. Njẹ a ti fi ṣe arikọgbọn lẹyin ogun abẹle.

 

 Ẹ ma jẹ ka tanra wa jẹ, iwe yẹn, a ti wo o, o ti gunmọ, o wa lọwọ wọn, Buhari lo ni ki wọn gbe e pamọ. Ta a ba tun un ṣe, ko si bo ṣe le pẹ to, idi irannu ta a maa wa ree. Nitori gbogbo ọrọ ta a ko wa ni wọn n ge, ijọba ibilẹ meloo lo wa l’Ekoo, Ogun (20) iye eeyan to n gbe l’Ekoo nkọ, o le ni ogun miliọnu.

 

Ipinlẹ Ogun naa ni ijọba ibilẹ Ogun, awọn ko si to Eko, Kano ni ijọba ibilẹ mẹrinlelogoji, gbogbo wọn ni wọn n gbowo lọwọ ijọba apapọ loṣooṣu.

 

O yẹ ka dupẹ lọwọ Jonathan to tiẹ jẹ ka ṣe atunyẹwo iwe ofin yẹn, ko sẹni to ṣee ri, awọn eeyan ni ko ma ṣe e, o ṣaa ṣe e. Akọkọ to maa ṣẹlẹ ninu ijọba alagbada niyẹn, pe ki wọn fun wa lanfaani lati yẹ iwe ofin wo ka si tun un ṣe.

 

Ṣe ẹ dẹ ri tawọn ti wọn n sọ pe ki kaluku maa lọ tiẹ lọtọ lorilẹ-ede yii, ki i ṣe bẹẹ. A le bara wa lo, awa ni a ko wo ofin Amẹrika ta a la n lo bo ṣe yẹ ka wo o, a o ṣe e bo ṣe yẹ ka ṣe e tan. Ṣe teeyan ba fẹẹ kọṣe ẹnikeji, ṣe aabọ ni wọn n ṣeru ẹ ni, abosi niyẹn.

 

Ọgbẹni to dẹ n ṣe Olori oko nisinyi, nigba ti Jonathan pe e, o loun o ba wọn ṣe. Ṣugbọn gbogbo nnkan to yẹ ka, wo ka si tun ṣe, fun igba akọkọ, a  ṣe e a si kọ ọ sinu akọsilẹ yẹn, emi naa ba wọn lọ sibi ipade naa (Constitution Conference).  A ṣe e, a gbe  e fun wọn, eyi to ku ni pe ki wọn gbe e fawọn aṣofin.

 

 

Kin ni ọna àbáyọ?

 

Ohun naa ni mo ṣe n sọ pe eeyan gbọdọ le jokoo ko ba awọn eeyan sọ otitọ ọrọ. Ka sọ fun wọn pe ba a ṣe n ṣe yii, ko bojumu,pe ibi ta a n lọ yii, ẹtan ni. 

 

Eeyan gbọdọ jẹ ki wọn mọ pe iṣesi ologun yatọ si ti oloṣelu, bologun ba paṣẹ, bẹẹ ni, ẹni ti ko ba ṣe e , kele ofin yoo gbe e, keeyan ṣe e naa lo si le jẹ anfaani.  Ṣugbọn iyẹn kọ la maa gbe wa si ọdọ oloṣelu.

 

Ẹ jẹ ki kaluku da ọmu iya ẹ gbe, mi o ni ki wọn tu ilu ka, ṣugbọn mo n sọ ọ pe abosi la n ṣe, kinni yii o wọọki, ẹ wo owo nla ti wọn fi n ra ọkọ funra wọn, ebi dẹ n pa araalu. Ẹ jẹ ka sọ ọ bo ṣe yẹ ko ri, ka tiẹ le ni alaafia niluu.

 

Wọn n sọrọ dọla, ileeṣẹ wo ni ki i ko nnkan wa lati oke okun. A n sọrọ burẹdi pe o wọn, ko sohun ti ko wọn. Ebi pọ ju ara dẹ n kan araalu.

 

Njẹ ijọba ologun le tán iṣoro Naijiria pẹlu awọn ohun to n koju wa yii?

 

Ọrọ ologun kọ lo wa nilẹ yii, ti wọn ba debẹ,ki ni wọn fẹẹ ṣe. Iṣẹ ologun pẹlu iṣẹ oṣelu yatọ sira wọn, nitori tologun ba de, awọn aṣofin ni wọn maa kọkọ yọ danu pe awọn ko fẹ.

 

Ẹ jẹ ki n sọ iriri mi fun yin, nigba ti wọn yan mi pe ki n lọọ ṣe gomina nipinlẹ Ondo. Ologun ko ni aṣoju lati ẹkun-jẹ-kun ti yoo ṣoju ilu kan,nigba to dẹ jẹ pe awọn ẹkun yii wa nijọba alagbada, bawo niwọ ologun ṣe maa le ba wọn sọrọ.

 

Mo waa ka awọn iwe Baba Awolọwọ titi, nigba ti mo n de Ondo, mo ri i pe aleebu ni kologun fẹẹ ṣejọba,nnkan aa maa bajẹ si i ni.

 

Niṣẹ ni mo pe akọwe ijọba, mo ni bawo la ṣe fẹẹ desalẹ lọdọ awọn eeyan, mo ni ko jẹ ka kọkọ ṣepade pẹlu awọn Akọwe agba naa lati mọ bi nnkan ṣe n lọ ni minisiri wọn.

 

Mo n ṣepade ni Mọnde, Wẹsidee, mo si n lọ sawọn abule lọjọ Tọsde lati le di alafo awọn ọnarebu ti ko si nijọba ologun, oun ni mo fi mọ bi nnkan ṣe n lọ.

Ijọba ologun ko bọ si i, ẹni to ba n ronu iru ẹ, ki wọn ma dan an wo. Ki wọn jẹ ka ṣe e bo ṣe yẹ, ko yee jẹ ariwo Mista Prẹsidẹnti lawọn eeyan kan yoo maa pa kiri. Ani ebi pọ niluu, iyan pọ niluu, ko si aabo, wọn ni wọn tun ji Ọjọgbọn kan gbe laipẹ yii. Ki lo n fa, awọn ṣọja naa ti n bẹ kiri nitori aabo,kinni yii ko kunna, bi nnkan ko ba dẹ kunna, ẹ n tanra yin jẹ ni.  

 

Gbogbo nnkan lo gbówó lori ni Naijiria bayii nitori owo Dọ́là to ba aye Naira jẹ, bẹẹ a o ko na Dọla, ki lo fa inira fun wa?

 

Ko si ileeṣẹ kan nilẹ yii ti ki i ra nnkan oke okun ki wọn too le ṣiṣẹ wọn, atubọtan ẹ niyẹn.

 

Banki agba ilẹ wa lo yẹ ko wa nidii iṣakoso ohun ta n pe ni Fiscal Policy (bijọba ṣe n nawo ati bi wọn ṣe n gba owo ori lati tun ọrọ aje ṣe), nitori ohun tẹ ẹ ba pa wọle lẹ maa na.

 

Ki la n mu wọle, gbogbo owo epo wa, gbogbo sọbsidi ti wọn lawọn yọ, ki lo n jẹ bẹẹ. Ole ti wọn ja nidii kinni yẹn, wọn o ti i sọ otitọ inu rẹ o, ole ti wọn ja nidi ẹ ko ṣee ko o.

 

Bi wọn ṣe n ji epo lọtun-un losi, elo la n mu wọle nisinyi. To o ba tun wa ri gbese ta a jẹ. Nigba ti Ọbasanjọ wa lori oye, o lọ kaakiri awọn orilẹ-ede ta a jẹ lowo pe ki wọn foju fo gbese yẹn da fun wa, wọn dẹ ṣe bẹẹ. Gbese yẹn tun ti tobi ju bẹẹ lọ nisinyi, nibo lowo ra si.

 

Dọla ta a n pariwo, ta a o ba ni owo nipamọ lati fi sọ pe bayii la to, ohun ti wọn fi n mọ ohun ta a wọ̀n niyẹn.  Bowo ba ṣe lagbara si ni wọn ṣe n wo o lagbaye.

 

Dọla dẹ ree, gbogbo agbaye lo n na an. To o ba fẹẹ lọ ra ọja ni China paapaa, dọla lo maa san, beeyan fẹẹ lọ si Kutọnu lasan, oo le gbe naira lọ sibẹ, ṣugbọn agbara naira wa da, ko si nnkan to ti i lẹyin, iyẹn lo ṣe n fọ.

 

Abosi dẹ ni. Ẹwo gbogbo nnkan ti Emefiele dan wo, haa, oun tun n ya awọn eeyan lowo ni Dọla lasiko tiẹ. Ileefowopamọ agba ilẹ wa wa di banki kekere olokoowo, haa, iru ki la kan yii.

 

A wi tan, oun naa loun fẹẹ di prẹsidẹnti, o lọọ ra mọto rẹpẹtẹ jọ. Hmmmm, Ọlọrun aa kọ wa mọ ọn ṣe o.

 

Owo oyinbo di 1,400 fun pọn-un kan, lọjọ ti mo ti daye mi o tiẹ gbọ ọ ri, a ti fẹẹ da bii Zimbabwe niyẹn o, diẹdiẹ ni alabọrun n dẹwu, aa daa lọla, ẹnu ẹ la wa yii o.

 

Ẹ ti sọ pe ẹ maa kuro ni Naijiiria bi Tinubu ba wọle sipo aarẹ, ki lo de ti ẹ ko ti i mu ileri naa ṣẹ latigba ti Aarẹ Tinubu ti wọle?

 

Mo ti lọ fun bii ọsẹ mẹfa nisinyi. Ṣe ẹ ri ọjọ ori ti mo de yii, ibi to ba wu mi ni mo le gbe, nnkan to ba wu mi ni mo le ṣe.

 

Ọdun mẹẹẹdọgbọn (25 years) ni mo ṣe niṣẹ ologun, ọdun yii naa lo pe ọdun mẹẹẹdọgbọn ti mo ti ba wọn bẹrẹ oṣelu, to o ba pa a pọ, o jẹ aadọta ọdun, ṣe iyẹn o to.

 

Ṣe mimọ- ọn ṣe temi ni abi t’Eledumare, ti mo ba ni mo fẹẹ lọ lonii, mo tun n lọ naa niyẹn. Ṣugbọn  ilu ẹni nilu ẹni, nnkan to ṣẹlẹ ni pe nigba ti idibo n bọ, wọn ran eeyan waa ba mi pe ki n ma binu, ki n ni suuru.

 

Nigba tawọn agbalagba dẹ ti wa, inu ọfiisi mi yii naa ni ọga awọn APC, Baba Olusi, Adajọfẹyinti Ọlọrunninbẹ, ẹni ọdun mẹrinlelaadọrun (94 years) atawọn olori wa yooku, wọn ni ki n ni suuru. Wọn lawọn gba pe wọn ti ṣeka fun mi ṣugbọn ki n ni suuru.

 

Ko sẹni to le da mi duro ti mo ba fẹẹ jade, mo ṣẹṣẹ de paapaa ni, ko sẹni to yọ mi lẹnu.  Ṣugbọn beeyan ba wa lọhun-un yẹn naa, eeyan aa maa ranti ile pe oun lẹgbọn, oun laburo nile, ọmọ, ẹbi tebi n pa. Igba ti wọn dẹ ti waa bẹ mi pe ki n ni suuru, mo gbọ.

 

Nibo la o ti i de ninu oṣelu, mo ti de ori oke pata ti mo jokoo si yara Olori oko ninu Villa, mo jokoo sori bẹẹdi ti mo ba Baba ṣepade. Wọn tun gbe mi pitipiti lai ṣẹ, o tun di inu ọgba ẹwọn Kirikiri, ki n le ri idakeji aye.

 

Beeyan ba sọ fun mi ri pe mo maa debẹ yẹn maa jiyan, nitori ki ni mo fẹẹ ṣe to fẹẹ gbemi debẹ.

 

Baba to da oṣelu silẹ ni Naijiria, Herbert Macauley, ẹgbọn mama –mama ni.

 

Ẹru obodo temi o, ẹni ti yoo wọdo lominu n kọ. Anfaani ni Ọlọrun fun mi lati mọ bi oke ati ilẹ agbara ṣe ri, ki lo n bọ loke tilẹ o gba, anfaani ti ko wọpọ ni mo ri gba, to ba wu mi lati lọ, ma a lọ, to ba dẹ tun wu mi, ma a duro sile, kawọn ṣaa ṣe e ire.

 

Baba Olusi sọ fun mi pe aa wu awọn k’emi naa ṣe bii awọn gomina G5 ti wọn lọọ ki Aarẹ, pe k’emi naa lọọ ki i kuu oriire.

 

Mo sọ fun wọn pe ti ẹwọn ti mo lọ yẹn, ọgbọn nla ni mo lọọ kọ nibẹ, Ọlọrun ni mi i lo ni, lati mọ pe aye kan wa to yatọ si eyi ta a ti n ba bọ. Emi ti gboju nibẹ, mo si ti tẹle ọrọ Ọlọrun to sọ pe teeyan ba ṣẹ ọ, tiwọ ko ba dariji i, o loun naa funra oun ko ni i dari ji oluwa rẹ. 

 

Ṣugbọn ni ti ẹlẹẹkeji yẹn, pe ki n gbe agbada kọrun ki n tun lọọ ki Aarẹ l’Abuja, ki ni mo fẹẹ  sọ nile. Mo ni mi o ba a ja, mi o ṣe ẹgbẹ wọn.

 

Awa naa wa ni kootu, ọmọ ẹgbẹ to n ṣoju Ilẹ Yoruba ni mi, ọkan ninu awọn alakooso ẹgbẹ ni mi, a wa ni kootu, ma a waa gbe agbada, ma a ni mo n lọọ ki Aarẹ, ki ni mo maa ni mo n wa. Mo ni mi o ba wọn ja, ṣugbọn iru iyẹn ko ṣee lọ fun mi, ẹgbẹ wa ko dọgba

 

Njẹ iṣọkan le pada si PDP mọ bayii pẹlu bi nnkan ṣe n daru lati oke wa titi de awọn ipinlẹ?

 

Ko si ẹgbẹ ti aawọ ki i ti i ṣẹlẹ, ṣugbọn ti ifẹ ba wa, eeyan aa ṣẹgun. O ṣẹlẹ lẹgbẹẹ tiwa naa, ko sibi ti ko ti ki i ṣẹlẹ.

 

Ti a ba mu ibo Atiku mọ ti Obi ati Kwakwanso, ẹ o mọ pe a ti na awọn araabi pa niyẹn, sugbọn ki lo de ti ko ri bẹẹ, iyẹn la ni lati ba ara wa sọ.

 

Ti a ko ba wo aṣiṣẹ ta a ṣe tẹlẹ, ai fini peni, aifeeyan-peeyan to ko ba wa, ka  ṣe atunṣe, bakan naa ni yoo maa ri lọ, afi ta a ba ṣehun to yẹ ka ṣe.

 

A gbọdọ tun ile wa to, awọn ti wọn fẹẹ digba-di- agbọn, iyẹn kọ ni nnkan to wa nilẹ bayii, ẹ jẹ ka kọkọ wo o, ki lo fa aawọ kaakiri gbogbogbo.

 

Awọn to da ẹgbẹ yii silẹ ṣe daadaa, Bọla Ige pẹlu awọn to da ẹgbẹ wa silẹ, ṣe Bọla Ige le jokoo ti Alex Ekwueme. Abi Nwobodo ati Ekwueme le rira wọn soju. Solomon Lar ati Ciroma, abi Rimi lo maa ba Ọjọgbọn Aminu sọrọ, ati Bamanga Tukur, gbogbo ifẹ ti wọn ni sira wọn jẹ ki ilu yii to, notori wọn pin Naijiira sọna mẹfa ni, wọn dẹ pin ipo sọna mẹfa.

 

Ipo Aarẹ, Igbakeji aarẹ, olori ile igbimọ aṣofin, Abẹnugan ile aṣofin, Akọwe ijọba ati Alaga ẹgbẹ lapapọ.

 

Ti ẹnikan ba lọ soke, ẹnikeji aa lọ sisalẹ, gbogbo awọn ẹya ti ko pọ naa n ri nnkan mu lọ sile. Ko si ki i ṣe ibi nikan ni wọn ti ṣe e, ohun ti wọn n ṣe ni Swizerland titi dọla niyẹn, wọn n pin in ni, bẹnikan ba ṣe, ẹnikeji naa aa ṣe.

 

Nigba temi de, mo wo o pe ẹgbẹ yii nikan lo kari ni Naijiria, ko sibi to o le de to o ni i ba PDP. Nigba to dẹ ti di pe ki wọn maa pin-in, iwọ lo maa gba eleyii, emi ni mo maa gba iyẹn, wọn tọwọ bọ ọ, mo dẹ sọ fun wọn pe bẹẹ yẹn kọ, awọn baba to da a silẹ ko ṣe e bayii.

 

Tibi fẹẹ di ṣiamaanu, tọhun fẹẹ di ṣiamaanu, a o dẹ ti i wadii nnkan to gbe wa debi ta a de, ẹ waa lẹ ẹ fẹẹ maa dọgbọn si i. Awọ ya, ẹ fẹẹ dọgbọn si i, ẹ o beere ki lohun to fa awọ ya. Ki la le ṣe to le fi ṣe rẹgi pada, mo sọ fun wọn pe ti wọn o ba ṣeyẹn, wọn n tanra wọn jẹ ni. 

 

Wọn tun ti fẹẹ bẹrẹ ti Aarẹ bayii, ṣe ba a ṣe fẹẹ ṣe e naa ree. Emi n reti ọjọ ti wọn maa pe mi, ma a da wọn lohun, ka sọ ootọ ọrọ funra wa. Ibo mi-in ta a maa di tun di 2027, ta lo mọ ẹni to maa wa laye ninu wa nigba naa, ṣugbọn ta a ba tun ile wa ṣe, ta a ṣe bawọn baba yẹn ṣe ṣe e, a o niidi ariwo, o maa ṣee ṣe. Ẹni to wa nipo aarẹ bayii ṣẹṣẹ bẹrẹ ni, ọdun mẹrin lo maa lo. Ti awa ba le fasiko yii tun nnkan tiwa to, o maa ṣee ṣe fun wa, a ṣi ni asiko bayii.

 

Ta a o ba ti ṣe bẹẹ, a n tanra wa jẹ ni, emi o tiẹ ni ba wọn da si i.

 

Awọn eeyan sọ pe ẹyin lẹ o jẹ ki ẹgbẹ PDP Eko rọwọ mu, wọn lẹyin ni ‘Baba sọ pe’ inu ẹgbẹ naa, ṣe loootọ ni?

 

Emi ni alaga akọkọ ti wọn dibo yan lẹgbẹẹ PDP nilẹ Yoruba, mo ṣiṣẹ titi, mo di Igbakeji alaga fun gbogbo Ilẹ Yoruba, mo tun di Igbakeji alaga apapọ, mo si le fọwọ sọya pe ọdun mẹwaa ni mo lo nipo Igbakeji alaga apapọ yẹn.

 

Awọn ti wọn ba n sọ pe emi ni mi o jẹ ki PDP rọwọ mu l’Ekoo, alabosi ni wọn.

 

Beere lọwọ wọn pe ọjọ wo ni mo wa sọdọ wọn ti mo n tọka pe ẹnikan ni ki wọn mu, ki wọn ma mu ẹnikan. Yoruba maa n sọ ọ pe ija lo do torin dowe, emi o dẹ ni i si nidii idọti.

 

Ara nnkan ti mo ṣe sọ pe o yẹ ka sọrọ lẹka apapọ PDP naa niyẹn, ka yanju gbogbo iwa abosi ati iwakiwa ti kaluku n hu, ki i ṣe pe ka kan maa le ipo kiri.

 

Ẹ n beere  pe ki lo de ti PDP ko rọwọ mu l’Ekoo, ṣe bi wọn ṣe n dibo ni wọn di i l’Ekoo yẹn, ṣebi wọn kọ ọ ni.

 

Iwọ beere lọwọ ẹnibọdi boya wọn fẹ pati wọn yẹn abi wọn o fẹ. Lọjọ ti Buhari sọ pe awọn ti ra maṣinni tuntun fun ibo didi, a ṣe pati ninu ile yii, a n ro o pe ohun tawọn eeyan ba fẹ lo maa waye.

 

O wa di ọjọ ibo, ẹ waa ni kinni kan ṣẹlẹ, pe wahala kan ṣẹlẹ, wọn waa n fọwọ kọ ibo, gbogbo ibo ti wọn ni wọn di l’Ekoo, ṣebi wọn fọwọ kọ ọ ni, abosi ti Buhari ṣe yẹn, Ọlọrun aa bi i.

 

Ṣe inu awọn eeyan dun l’Ekoo, igba kan ta a tun winni, Atiku naa wa sibẹ to waa bẹ wa, o ni ka ma binu, pe oun loun ba a yi i, o tun sọ ọ lẹnu ọjọ mẹta yii.

 

Nigba  ti wọn fẹẹ dibo gomina to kọja yii, gbogbo awọn oludije yẹn wa sibi gẹgẹ bi wọn ṣe maa n ṣe, Jandor naa wa. Ṣugbọn ọmọ to ṣe daadaa ju ni Rhodes Vivour, baba ẹ atemi la jọ wa ni yunifasiti.

 

Mo pe baba ẹ, mo ni ko jẹ ki Jandor ṣe gomina, nitori o ju Vivour lọ, ki Vivour ṣe Igbakeji ẹ, pe ko ma si aawọ.

 

Ọrọ ti Jandor sọ lọjọ naa daa ṣugbọn ko to ti Vivour. Ṣugbọn niṣe ni Jandor sọ pe oun ti ba Arabinrin Denrele sọrọ ko too ku, iyẹn ti sọ pe toun ba maa mu Igbakeji, koun lọọ mu un n’Ikorodu.

 

Mo ni abi o mugbo ni, isọkusọ wo lo n sọ. Abosi lo ṣe. Ọjọ ti wọn tun maa dibo abẹle, iyẹn tun pe mi.

 

To ba jẹ pe wọn fi wọn silẹ pe ki wọn ṣe e, Vivour maa naa Jandor faya, ṣugbọn gbogbo ẹ naa, arikọgbọn ni.

 

Emi tirafu, nigba ti mo maa fi de, Vivour ti lọ sinu ẹgbẹẹ Labour, mo dẹ sọ fun Jandor pe ko ma debi mọ, mo sọ fun un pe alabosi ni. Ẹyin naa ẹ wo o to ba jẹ ninu ẹgbẹ wa lo duro si, teeyan ba ṣabosi, aa ba a nibẹ, eeyan ko le gbin ila ko ni agbọn loun maa ka nibẹ. Iyẹn ni mo ṣe n sọ fawọn eeyan wa pe ki wọn ni suuru, arikọgbọn lohun to ṣẹlẹ yẹn, iru ẹ o dẹ le ṣẹlẹ mọ.

 

Emi o ki n ba wọn da si, agbalagba to waa da si i, mo forukọ bo wọn laṣiiri lo jẹ ki n da si i. Ẹ wo esi tawọn mejeeji ni, ti wọn ba da a pọ, wọn aa na Sanwo-Olu.

 

Sunday Igboho tun ti n halẹ lori ọrọ Yoruba Nation, ki lẹ le sọ si eyi?

 

Ma a bẹ Sunday Igboho pe ko ni suuru, suuru lere pupọ, gbogbo ariwo ati wahala, ko sẹni to mọbi to le ja si o.

 

Ani ki wọn gbe iwe ofin wa ta a tun ṣe jade, ki ọgbẹni to wa nibẹ nisinyi gbe e sita, ko jẹ ki gbogbo aye ri i.

 

Oju wo lẹ fi wo aṣẹ ti Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ pa fawọn ọba alaye nipinlẹ Ọyọ, nigba to ni ki wọn dide fun Gomina Ṣeyi Makinde nita gbangba?

 

Ko ṣee sọ pe agba ṣẹ, ko yẹ ko jade lẹnu iru emi bayii, sugbọn iwe ofin wa ti kọ ohun ti kaluku jẹ lagbo.

 

Ta lo yan ọba, awọn afọbajẹ aa kọkọ jokoo, wọn aa mu ẹni ti wọn fẹ, wọn aa forukọ ẹ ranṣẹ si gomina, gomina lo maa fọwọ si i.

 

Nigba ti Baba ni ki wọn dide, ki wọn jokoo yẹn, wọn le ṣe e lọna mi-in. A a le maa ṣidi ara wa sita, ti wọn ba ṣẹ, ti wọn n ba gomina ja, gomina le mu wọn, agbara gomina pọ, ofin wa lo fun wọn lagbara.

 

Emi o mọ ohun to ṣẹlẹ gan-an o, ṣugbọn ti wọn ba beere lọwọ emi pe bawo lo ṣe yẹ ko ri, emi aa ni wọn o ba pe wọn sinu ile, ki wọn ba wọn sọrọ nibẹ niṣoju gomina naa.

 

Ọdun mẹjọ ni gomina yoo lo bo ti wu ko pẹ to, ṣugbon awọn ọba, igba t’Ọlọrun ba lo ya ni, iyẹn lo fi yẹ ki wọn sọ ọ lasọye pọ, bemi ṣe ri i niyẹn. Iru nnkan bẹẹ yẹn ko le ṣẹlẹ l’Oke Ọya.

 

Emi o mọ nnkan to fa a o, ṣugbọn nnkan kan ni lati fa a ki Baba too binu bẹẹ.

 

Awọn eeyan dẹ ti n yi ọrọ yẹn, wọn ti n sọ oriṣiiriṣii. Ọmọ Yoruba, mo fẹẹ bẹ wa ni, ẹ jẹ ka kora wa jọ, e jẹ ka nifẹ ara wa.

 

Ti wọn ba n sọ nipa ọlaju, awa lakọkọ. Awa la ni dokita akọkọ, lọọya akọkọ, biṣọọbu akọkọ ni gbogbo ilẹ Adulawọ.

 

O tojọ mẹta ta a ti n ba a bọ o, ohun tiwọ naa ko ba ni i gba, ma ṣe e fọmọlakeji.

 

Ẹ jẹ ka nifẹẹ ara wa, iyẹn la o ni, ki la n wa t’Ọlọrun o fun wa nilẹ Yoruba, a ni alumọni, a ni nnkan ọgbin.

 

Ọba Eledumare n wo wa o. Ẹ jẹ ka nifẹẹ ara wa, nitori nnkan temi ri to ku diẹ kaato nilẹ Yoruba niyẹn o.

 

Ki lo n tan eeyan fun, ko si iru irọ to o le ni o pa ti ko ni i tuka lọjọ kan. Ẹ jẹ ka ṣeere o.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI