Kò sí ẹnikẹ́ni tó fẹ́ẹ́ pa mí o - Yahaya Bello pariwo síta - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, October 23, 2023

Kò sí ẹnikẹ́ni tó fẹ́ẹ́ pa mí o - Yahaya Bello pariwo síta


Gomina Yahaya Bello ti ipinlẹ Kogi ti oariwo sita wi pe ko si ẹnikẹni tabi agbebọn kankan to fẹẹ pa oun, ati pe iroyin naa to jade wi pe ori ko oun yọ lọwọ awọn agbanipa kii ṣe otitọ.

Ọjọ Aiku, Sannde ana ni kọmiṣanna f'ọrọ eto iroyin n'ipinlẹ Kogi, Kingsley Fanwo sọ pe awọn agbebọn kan ti wọn wọ aṣọ ologun ṣina ibọn bolẹ fun mọto Yahaya Bello, to si jẹ pe ori lo ko o yọ.

Fanwo sọ pe asiko ti Gomina n lọ sibi eto kan ti wọn pe e si niluu Abuja ni iṣẹlẹ ọhun waye, to si ni awọn ẹṣọ aabo gomina lo koju wọn, ko to di pe awọn agbebọn naa salọ.

Ṣugbọn Bello nigba toun funra rẹ n fidi iroyin ọhun mulẹ, o ni irọ to jinna si otitọ ni pe awọn kan fẹẹ pa oun.

O ṣalaye pe lotitọ ni awọn ologun da oun ati ikọ akọwọrin oun duro loju ọna marosẹ Lọkọja si Abuja, ṣugbọn kii ṣe nipa ija tabi ogun.

O ni aawọ lo waye laaarin ẹṣọ aabo oun ati awọn oṣiṣẹ ologun naa, ati pe iṣẹ wọn ni wọn n ṣe, to si ni wọn ti pada yanju ẹ laaarin ara wọn.

Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe "Ni nnkan bi aago meji ọsan oni (Sannde), mo gbera lati ilu Lọkọja, mo si n bọ ni Abuja. Irin ajo naa n lọ bo ti yẹ pẹlu ikọ akọwọrin mi.

"Nigba ti yoo fi di deedee agogo mẹrin irọlẹ, awọn akọwọrin mi, paapaa awọn ẹṣọ aabo ni aawọ pẹlu awọn ẹṣọ aabo miran ti wọn wa loju ọna.

"Loju ẹsẹ la ti da sii, ti a si yanju ẹ. Lati ibẹ, titi ti a di de ilu Abuja, ti mo si lọ si awọn ibi ti mo fẹẹ lọ, ko si nnkan to sẹlẹ, ayọ ni.

"Igba to ya ni mo bẹrẹ sii gbọ oriṣiriṣi lori ayelujara wi pe wọn fẹẹ pa mi. Mo fẹẹ sọrọ idaniloju, ki n si tan imọlẹ sii fun gbogbo ọmọ Naijiria wi pe ko si ẹnikẹni to fẹẹ pa emi Yahaya Bello, gomina ipinlẹ Kogi."

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI