'Banga' yinyin ti di eewọ ni Kwara lasiko ọdun Keresimesi - Ọlọpaa - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, December 20, 2023

'Banga' yinyin ti di eewọ ni Kwara lasiko ọdun Keresimesi - Ọlọpaa


Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kwara lọjọ kọkandinlogun, oṣu kejila, ọdun 2023 ti sọ pe yinyin awọn Banga ti di eewọ fun gbogbo araalu lasiko ati lẹyin pọnpọnṣinṣin ọdun Keresimesi ati ọdun tuntun.
 
Ọga ọlọpaa ipinlẹ naa,Victor Ọlaiya lo sọ eyi di mimọ ninu atẹjade to gbe sita lati fi ṣe ikilọ fun araalu ati alejo.

Nibẹ lo ti sọ pe ko nii si anfaani fun ẹnikẹni lati yin awọn ohun alariwo to n dun bii ibọn, eyi ti awọn eeyan fi n ṣayẹyẹ ọdun, nitori eto aabo.

O gba awọn araalu lamọran lati ṣọdun niwọnba, ki wọn si kiyesara awọn to n kọja lagbegbe wọn, nitori pe oju lalakanfinṣọri.
 
Siwaju sii lo ni k'awọn yago fun awọn iwa to le ko ẹru si araalu lọkan, paapaa nipa dida alaafia ilu ru.
 
Nigba to n tẹsiwaju, o sọ pe gbogbo awọn nnkan to n dun bii ibọn ti wọn le si ba dukia jẹ, iyẹn  bii Banga.

Ọga ọlọpaa ni ẹnikẹni ti ọwọ ba tẹ yoo fi ẹnu fẹra bi abẹbẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI