Lọjọ ti Gomina Makinde gbe ọpa aṣẹ fun Ṣọun Ogbomọṣọ tuntun, Ọba Ghandi - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, December 20, 2023

Lọjọ ti Gomina Makinde gbe ọpa aṣẹ fun Ṣọun Ogbomọṣọ tuntun, Ọba Ghandi


Ẹsẹ ko gbero niluu Ogbomọṣọ, ipinlẹ Ọyọ laipẹ yii nigba ti Gomina Ṣeyi Makinde gbe ọpa aṣẹ fun Ṣọun tiluu Ogbomọṣọ tuntun, Ọba Ghandi Ọlaoye.
 
Igbakeji Aarẹ Naijiria tẹlẹri, Ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajo; Gomina Ademọla Adeleke tipinlẹ Ọṣun; Ọọni Ile-Ifẹ, Ọba Adeyẹye Ẹnitan Ogunwusi; Olubadan tilẹ Ibadan, Ọba Lekan Balogun; Olu tiluu Warri, Ogianne Atuwase kẹta, ati awọn miran ni wọn peju-pesẹ.

Gomina Ṣeyi Makinde ati Ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajo ni wọn jọ kọwọrin wọ Papa Iṣere Ṣọun lọjọ naa.
 
 
Nibẹ ni Gomina Makinde ti rọ Ṣọun tuntun naa lati fi ifẹ han si gbogbo ọmọ ilu, ati pe ko gbajumọ ọrọ idagbasoke ati eto ọrọ ilẹ Ogbomọṣọ.
 
O ni eto aabo ṣe pataki pupọ lasiko yii, nitori pe ki ọba tuntun naa ṣiṣẹ takuntakun lati rii pe eto aabo ko mẹhẹ nipa ajọṣepọ pẹlu awọn ti ọrọ naa kan.
 

Makinde ni, lai si eto aabo to pe ye, ko le si idagbasoke tabi ilọsiwaju kankan niluu, fun idi eyi, o ni ki kabiyesi fọwọsowọpọ pẹlu awọn ileeṣẹ eleto aabo niluu naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI