Gbajumọ Puromota fẹẹ fi ẹbun ọdun tọrẹ fun awọn akẹkọọ l'Abẹokuta - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, December 20, 2023

Gbajumọ Puromota fẹẹ fi ẹbun ọdun tọrẹ fun awọn akẹkọọ l'Abẹokuta


Gbajugbaja puromota nni, Oloye Arẹmu Bamgboye ti ọpọ awọn ololufẹ rẹ mọ si Ajiki-Olu ti ṣetan lati fi ẹbun ọdun ta awọn akẹkọọ lọrẹ niluu Abẹokuta.

Oloye Ajiki-Olu to ti gbe ọpọ awọn olorin Fuji, Musulumi ati bẹẹbẹẹlọ, to fi mọ awọn oṣere tiata dide lorileede Naijiria lo fẹẹ fi ẹbun ọdun ta awọn akẹkọọ ile-ẹkọ to ti jade, iyẹn Anglican High School lọrẹ.

Gẹgẹ bi iroyin to tẹ AWIKONKO lọwọ ṣe sọ, wọn ni ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu kejila, ọdun ti a wa yii ni ọkunrin naa fẹẹ fi ẹbun ọdun yii tọrẹ.

Ninu ọrọ ti ẹnikan to sunmọ Ajiki-Olu, ẹni to ni ka fi orukọ bo oun laṣiri ṣe sọ, O ni kii ṣe akọkọ ree ti ọkunrin naa yoo maa ta awọn eeyan lọrẹ.

Ẹni naa sọ pe lara awọn ohun ti Ajiki-Olu fẹran ni lati maa ta awọn alaini tabi awọn to ku diẹ kaato fun lọrẹ, eyi lo fa a to fi pinnu lati fẹmi imoore han si Ọlọrun nipa fifi ẹbun ọdun tọrẹ f'awọn eeyan.

Akẹkọọ ti ko din ni ẹẹdẹgbẹta ni yoo jẹ anfaani ẹbun ọdun yii gẹgẹ bi a ṣe gbọ, ati pe awọn nnkan bi ounjẹ, owo ati dukia ni Ajiki-Olu yoo fi tọrẹ lọjọ naa.

Nigba toun funra rẹ n fidi rẹ mulẹ, Ajiki-Olu sọ pe lara iṣẹ ti Ọlọrun fi ran oun ni aanu ṣiṣẹ, ati pe o jẹ ọna ti Adẹdaa fi n bunkun oun, to si n mu ki ileeṣẹ oun maa tẹsiwaju ni gbogbo igba.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI