Noah ati Rajay pa ọrẹ wọn nitori baagi irẹsi, ladajọ ba ni wọn yoo ṣọdun lẹwọn Kirikiri ni dandan - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, December 20, 2023

Noah ati Rajay pa ọrẹ wọn nitori baagi irẹsi, ladajọ ba ni wọn yoo ṣọdun lẹwọn Kirikiri ni dandan


Ile-ẹjọ Majisireeti to wa lagbegbe Yaba nipinlẹ Ekoo ti sọ pe awọn ọrẹ meji kan, Noah Tovohome ati Rajay Zannu lọ ṣọdun lọgba ẹwọn Kirikiri lori ẹsun ipaniyan.
 
Ọrẹ wọn kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Ṣẹgun Zusu la gbọ pe awọn mejeeji gbimọ pa danu lori baagi irẹsi merindinlogoji.
 
Iwaju Onidajọ Linda Balogun lawọn mejeeji ti kawọ pọyin lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii.
 
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, wọn niṣe ni Noah ati Rajay lẹdi apo papọ pẹlu awakọ Bolt kan to n gbe awọn ẹru Zusu bọ lati Sẹmẹ wi pe ko pa a, ko si ji baagi irẹsi rẹ gbe salọ.
 
Agbegbe odo Novo to wa ni Sẹmẹ la gbọ pe wọn ti lọ pade ọkọ naa, ti wọn si fọ igi mọ lori, ko to di pe wọn tiidanu sinu odo naa.

Lẹyin eyi ni wọn gbe awọn baagi irẹsi rẹ lọ sagbegbe Badagry, nibi ti wọn ti lọ ta a danu ni miliọnu kan aabọ din diẹ {N1.4m} naira fun obinrin oniṣowo irẹsi kan.

Agbefọba Chekwube Okeh to fẹsun kan wọn ṣalaye pe ọjọ kejila, oṣu kọkanla, ọdun 2023 ni iṣẹlẹ ọhun waye, to si ni wọn jẹbi tako iwe ọdaran ipinlẹ Ekoo labala 222 ati 223.
 
Bo tilẹ jẹ pe awọn mejeeji bẹbẹ, wọn si lawọn ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan awọn, ṣugbọn Onidajọ Balogun sọ pe ko tii sọrọ lẹnu wọn, bi ko ṣe pe ki wọn lọ gbatẹgun lọgba ẹwọn Kirikiri titi di ọjọ kejilelogun, oṣu kinni, ọdun 2024.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI