Bi o ni erongba lati dokoowo ile ati dukia lawọn agbegbe bii Lẹkki, Ẹpẹ, Ibẹju Lẹkki nipinlẹ Ekoo, abi o tiẹ ti dokoowo tẹlẹ, ẹ tete sunmọ ibi nitori awọn iroyin tuntun ti a fẹẹ pin pẹlu yin.
Kii ṣe iroyin tuntun mọ pe ijọba ipinlẹ Ekoo yoo bẹrẹ kikọ papakọ ofurufu agbaye miran ti agbegbe Lẹkki-Ẹpẹ, eyi ti yoo bẹrẹ lẹkunrẹrẹ lọdun 2024 yii.
Gẹgẹ bi awọn gbajugbaja iroyin ṣe gbe e jade, Kọmiṣanna fọrọ iroyin ati ilanilọyẹ, Ọgbẹni Gbenga Ọmọtọṣhọ lo kede rẹ sita, to si tun jẹ ko di mimọ pe ọpọ awọn akanṣe iṣẹ to n lọ lọwọ nijọba yoo pari lọdun.
Papakọ ofurufu ọhun la gbọ pe wọn n boju wo lati gba awọn arinrin-ajo to to miliọnu marun-un laarin ọdun kan.
Ori ilẹ ti ko din ni ẹgbẹrun mẹta aabọ ẹkita (3,500 hectares), ati pe owo ti ko din ni ẹẹdẹgbẹrun owo dọla ni wọn yoo fi pari ipele akọkọ iṣẹ naa.
Eyi yoo mu imugbooro ba eto ọrọ aje agbegbe Lẹkki, Ibẹju-Lẹkki nibi ti awọn ileeṣẹ bii Lekki Free Trade Zone, Seaport, ati ileeṣẹ ifọpo Dangote wa.
Idagbasoke ni iroyin yii jẹ fun gbogbo awọn to ti kopa ninu tabi dokoowo pẹlu ileeṣẹ Adron Homes nipa rira ilẹ si Eko City Estate to wa ni adojukọ ibi ti papakọ ofurufu yii wa.
Bẹẹ si ni Rehoboth Parks and Gardens Estate wa to wa niluu Ibẹju Lẹkki sunmọ papakọ ofurufu yii yoo wa.
Bi iwọ ko ba wai tii dokoowo, tete ma ṣe fi asiko ṣofo, nitori pe anfaani nla lo delẹ yii fun gbogbo awọn to ba wa nitosi agbegbe yii.
No comments:
Post a Comment