Makinde buwọ lu ẹkunwo owo oṣu fawọn oṣiṣẹ ile igbimọ aṣofin Ọyọ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, January 9, 2024

Makinde buwọ lu ẹkunwo owo oṣu fawọn oṣiṣẹ ile igbimọ aṣofin Ọyọ


Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ṣeyi Makinde ti buwọ lu ẹkunwo owo oṣu awọn oṣiṣẹ ile igbimọ aṣofin kaakiri ipinlẹ naa pẹlu ida marundinlogoji.
 
Olori ile igbimọ aṣofin ipinlẹ naa, Ọnarebu Debọ Ogundoyin lo sọ eyi di mimọ lonii, ọjọ Iṣẹgun, Tuside lasiko ti wọn n ṣe isin ajumọṣe fun awọn oṣiṣẹ ijọba nipinlẹ naa.

Gẹgẹ bo ṣe wi, o sọ pe ẹkunwo naa jẹ ida marundinlogoji owo oṣu, ajẹmọnu iṣẹ ti wọn n ṣe, ati ida ọgbọn fun awọn ajẹmọnu miran labẹ aburada ti wọn pe ni Negotiated Consolidated Legislative Salary Structure.
 
Bakan naa lo tun fi kun un pe ida mẹwaa yoo jẹ ajẹmọnu fun ti isinmi ranpẹ lẹnu iṣẹ, eyi ti a mọ si 'Leave Bonus'.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI