Awujalẹ fontẹ lu Ọmọọba Ogunbanjọ gẹgẹ bii Kobowore tiluu Odo Joborẹ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, February 25, 2024

Awujalẹ fontẹ lu Ọmọọba Ogunbanjọ gẹgẹ bii Kobowore tiluu Odo Joborẹ


Awujalẹ tilẹ Ijẹbu lapapọ, Alayeluwa, Ọba Sikiru Kayọde Adetọna, ti fontẹ lu ọmọ oye tuntun fun ipo Koborowe tiluu Odo Joborẹ, Ọmọọba Olufẹmi Ọlalekan Sunday Ogunbanjọ.

Bakan naa ni Awujalẹ tun ṣe akanṣe adura fun Ogunbajọ, pẹlu atilẹyin pe yoo pẹ lori ipo naa ju awọn tiṣaaju lọ.

Nibi eto ọhun to waye ni aafin Awujalẹ l’Ọjọbọ, Tọside, ọjọ kẹẹdogun, oṣu keji, ọdun 2024 yii niluu Ijẹbu-Ode, Kabiyesi ni inu oun dun pe awọn to mọ nipa aṣẹ, iṣe ati ede Yoruba ni awọn araalu yan sipo.

Nigba to n gba ẹnu Awujalẹ sọrọ, Orimọlusi tiluu Ijẹbu-Igbo, Ọba Lawrence Jayeọba Adebajo sọ pe awọn aṣeyọri ti ọmọ-oye naa ti ṣe siluu lo sọrọ fun un lati de ipo awọn baba-nla rẹ.


Orimọlusi wa gba ọba tuntun yii lamọran lati jẹ ọba to n tẹti gbọ ọrọ araalu, to si n ṣe ohun ti ilu n fẹ, nitori pe ohun kan ṣoṣo to le jẹ ko pe lori ipo naa niyẹn.

Bakan naa lo sọ pe ki Ogunbanjọ ma ṣe ṣoju saaju nigba to ba n gbe igbesẹ to nii ṣe pẹlu ilu ati araalu, ati pe ṣiṣe otitọ nijọba rẹ ni yoo gbe e leke.


Alaporu tiluu Ipẹru-Rẹmọ, Ọba Jimọh Adebamiro Quadri, ninu ọrọ tiẹ naa gba ọba tuntun yii lamọran pe ko gbiyanju lati lo ipo rẹ lati fi mu ọna abayọ rere ba ilu, nigba ti ipenija ba dide.

Lara awọn ọba to tun wa nibẹ ni Moyegeso tiluu Itele, Ọba Mufutau Kasali; Ebumawe tiluu Agọ-Iwoye, Ọba Abdulrasaq Adenugba; Limeri tiluu Awa, Ọba Abib Awobajo; Ogirimadagbo tiluu Ilodo, Ọba Isiaka Ajede.

Awọn miran ni Olisa tiluu Odo Jobore, Oloye Jimọh Shittu ti gbogbo wọn si gba kabiyesi tuntun lamọran pe ko ma ṣe tiju lati lọ gba amọran lọdọ igbimọ awọn ọba alaye fun ilọsiwaju ati idagbasoke ilu.No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI