Tinubu kii ṣe onidan lati wa ojutu sọna abayọ eto ọrọ aje Naijiria to fori ṣanpọn - Wolii Ayọdele - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, February 26, 2024

Tinubu kii ṣe onidan lati wa ojutu sọna abayọ eto ọrọ aje Naijiria to fori ṣanpọn - Wolii Ayọdele


Alaṣẹ ati olori ijọ INRI Evangelical Spiritual Church, Wolii Elijah Ayọdele ti sọ pe ko si idan kankan ti Aarẹ Bọla Tinubu le pa, eyi to le fi wa ojutu si bi eto ọrọ aje Naijiria ṣe fori ṣanpọn lasiko yii.
 
Wolii Ayọdele jẹ ko di mimọ pe ki eto ọrọ aje Naijiria to le bẹrẹ sii dara, yoo to asiko ti ọdun to n bọ tii ṣẹ 2025 ba ti n lọ s'opin.

Ninu atẹjade ti Wolii Ayọdele sọ, eyi ti akọwe iroyin rẹ, Ọgbẹni Ọṣhọ Oluwatosin fi sita laipẹ yii, agba Wolii naa jẹ ko di mimọ pe nnkan yoo tubọ maa buru sii bi ijọba ba kọ lati ṣe ohun to yẹ ki wọn ṣe lasiko.

O ni ko si ohun meji to fa ijakulẹ eto ọrọ aje to n ṣẹlẹ lasiko yii to kọja wi pe ijọba kọ lati tẹle amọran to le mu ọna abayọ wa si iṣoro to n koju wọn bayii.
 
“Ẹ ma jẹ ka tan ara wa jẹ, ẹgbẹ oṣelu APC ati PDP lo ti ja awọn ọmọ Naijiria kulẹ, ṣubọn eyi to pọ ju lo wa lati ọwọ APC.

“Idalabi yii si wa lori Tinubu nitori pe nitori ori rẹ ni nnkan ti bajẹ. Ki awọn ọmọ Naijiria tete mọ pe nnkan ko nii dara lọdun yii.

“Tinubu ko le pidan kankan, ati pe bi nnkan yoo ba fẹẹ dara, yoo fẹẹ to ipari ọdun to n bọ.

“Bi a ba tẹsiwaju lati maa gbadura, ti ijọba ko si gbe igbesẹ to yẹ, ohun kan naa lo ṣi maa ja si. Bi apẹẹrẹ, ijakulẹ nla ni eto ounjẹ iranwọ ti ileeṣẹ ẹṣọ aṣọbode gbe kalẹ, nitori pe kii ṣe ohun ti wọn ro tẹlẹ.

“Ki lo tiẹ de to fi jẹ pe asiko yii ni wọn ṣẹṣẹ bẹrẹ sii pin awọn irẹsi yii fawọn araalu? Awọn eyi ti wọn ti n gba lati ọjọ pipẹ sẹyin nkọ?

“Ki lo de ti wọn ko pin wọn sawọn ipinlẹ kaakiri orileede yii lai jẹ pe atọwọdọwọ ni wọn fi ṣe, ki wọn si ṣe ohun to tọ?’’

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI