Ọga ile-ẹkọ dero ẹwọn ọdun mọkanla, akẹkọọ-ọmọ ọdun mẹfa lo ja ibale rẹ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, February 10, 2024

Ọga ile-ẹkọ dero ẹwọn ọdun mọkanla, akẹkọọ-ọmọ ọdun mẹfa lo ja ibale rẹ


Ọdun mọkanla gbako ni ọga ile-ẹkọ kan ti wọn pe ni Jalaludeen Zakari to wa lati abule Burra to wa nijọba ibilẹ Ningi, ipinlẹ Bauchi yoo lo lọgba ẹwọn.

Gẹgẹ bi iroyin to tẹ wa lọwọ, ọkan lara awọn akẹkọọ to ti jẹ ọga agba ni wọn sọ pe Jalaludeen fipa ja ibale rẹ.
Onidajọ Nana Fatimah Jibrin ti ile-ẹjọ giga ipinlẹ Bauchi lo gbe idajọ kalẹ fun Jalaludeen.

Agbefọba Dayabu Ayuba to fẹsun kan ọkunrin naa nigba to n ba awọn akọroyin sọrọ ṣalaye pe awọn ẹlẹri to tako Jalaludeen lo sọ ọ di ero ẹwọn ọdun mọkanla gbako.

Ayuba ni ẹlẹri mẹta ọtọọtọ lo jẹri tako ọkunrin naa, ti ile-ẹjọ si ri pe o jẹbi ẹsun ti wọn fi kan an.

O ni bo tilẹ jẹ ọkunrin naa ko lo nknan ọmọkunrin rẹ lati fi ibale ọmọ ọdun mẹfa ọhun, bi ko ṣe ọwọ rẹ, ṣugbọn to sọ pe iwa ifipabanilopọ naa ni, to si ni ijiya ninu.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI