Sunday Igbho bẹ Tinubu lati fi Nnamdi Kanu silẹ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, February 26, 2024

Sunday Igbho bẹ Tinubu lati fi Nnamdi Kanu silẹ


Olori ẹgbẹ ajijangbara to n pe fun idasilẹ orileede Yoruba, iyẹn Yoruba Nation, Sunday Adeyẹmọ ti ọpọ mọ si Sunday Igboho ti rawọ ẹẹ si Aarẹ Tinubu lati fi olori ẹgbẹ ajijangbara toun naa n pe fun idasilẹ orileede Biafra, iyẹn Nnamdi Kanu.
 
Igboho ni bi ijọba apapọ ba fi Kanu silẹ lasiko, yoo ri aaye lati lọ tọju ara rẹ lọsibitu.
 
Ọkunrin naa to ṣẹṣẹ pada wọ Naijiria lẹyin ọdun mẹta to ti sa kuro, latari bi ijọba ana lorileede yii ṣe fẹsun kiko eronja ogun wọlu lọna aitọ kan lo sọrọ yii lonii, ọjọ Aje, Mọnde.
 
Igboho sọ pe ki ijọba wọgile gbogbo ẹsun ti wọn fi kan Kanu, ko le raaye tọju ara rẹ ti ko ya lati bi ọdun meloo sẹyin.
 
Bakan naa lo sọ ninu fọnran naa to jade laarọ oni pe ominira ilẹ Ibo ni Kanu n ja fun, fun ifẹ araalu ẹ si ni, kii ṣe ohunkohun.
 
“Ẹ dakun, ẹfi Nnamadi Kanu silẹ, ki ẹ si gbe oṣelu yii ti sẹgbẹ kan. Ọkunrin yii ko ṣe ohunkohun. Oni ni ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu keji, ọdun 2024.
 
“Ẹ fi silẹ, ẹ jẹ ko maa lọ gbe pẹlu awọn mọlẹbi ẹ. Ọkunrin yii kan n ja fun awọn eeyan rẹ ni ẹkun South East lasan ni, gẹgẹ bi emi naa ṣe n ja fun awọn eeyan mi nilẹ Yoruba.
 
“Ẹ fi silẹ, ẹ jẹ ko maa lọ. Ẹ fi Kanu silẹ. Ẹ dakun ẹ fi silẹ.”

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI