O tan! Alaga ẹgbẹ oṣelu PDP ni Kwara kọwe fipo silẹ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, March 25, 2024

O tan! Alaga ẹgbẹ oṣelu PDP ni Kwara kọwe fipo silẹỌnarebu Shuiabu Jimọh to jẹ alaga ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP ni ẹkun Ariwa ipinlẹ Kwara (Kwara North Senatorial Chairman) ti kọwe fipo rẹ silẹ.

Ọdun keji ree ti a gbọ pe Jimọh ti wa lori ipo ọhun gẹgẹ bi alaga, iyẹn lati ọdun 2022 titi di aisko to fi kọwe fipo rẹ silẹ.
 
Akọwe ẹgbẹ naa nipinlẹ Kwara, Ọgbẹni Abdulrahman Kayode lo tẹwọ gba iwe ifiposilẹ naa, gẹgẹ bi a ṣe gbọ.
 
Ninu atẹjade ti akọwe ipolongo ẹgbẹ naa, Oluṣẹgun Oluṣọla fi sita, o ni bi ọkunrin naa ṣe kọwe fipo silẹ lọ nibamu pẹlu bo tun ṣe fa gba ipo miran ninu ẹgbẹ ọhun.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI