Ọwọ Amọtẹkun tẹ Taofeek, ọmọ ọdun mẹrindinlọgbọn lori ẹsun ijinigbe l'Oṣogbo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, March 25, 2024

Ọwọ Amọtẹkun tẹ Taofeek, ọmọ ọdun mẹrindinlọgbọn lori ẹsun ijinigbe l'Oṣogbo


Ileeṣẹ eleto aabọ lẹkun Iwọ-Oorun Naijiria ti a mọ si Amọtẹkun, ẹka tipinlẹ Ọṣun ti sọ pe ọwọ awọn ti tẹ gendekunrin, ọmọ ọdun mẹrindinlọgbọn kan, Oyekọla Taofeek lori ẹsun ijinigbe.
 
Ọga agba fun ileeṣẹ Amọtẹkun l'Ọṣun, Ọgagun Bashir Adewinmbi lo sọ eyi di mimọ loni, ọjọ Aje, ọjọ karundinlọgbọn, oṣu kẹta, ọdun 2024.

Adewinmbi sọ pe oogun abẹnugọngọ ni Taofeek fi ba ọmọdebinrin, ọmọ ọdun mẹẹdogun kan, Mariam sọrọ nile rẹ to wa ladugbo Ita Ọlọkan niluu Oṣogbo lọjọ Satide, ọsẹ to kọja yii.
 
O ni bi ọmọbinrin naa ṣe de ile Taofeek niyẹn pariwo sita nigba ti oogun ọhun ka loju rẹ, ti ariwo naa si tẹ awọn eleto aabo aladani kan to pe ni COMSAIC lọwọ.
 
Loju ẹsẹ lawọn eleto aabo ọhun ti fa Taofeek le awọn Amọtẹkun lọwọ, ti awọn yẹn si foju rẹ han fawọn akọroyin.
 
Nigba to n jẹwọ, Taofeek ni kii ṣe akọkọ ree toun yoo maa tan awọn ọmọbinrin wa sile oun lati ji wọn gbe, ati pe oun ko mọ pe aṣiri maa pada tu.
 
Adewinmbi ti wa jẹ ko di mimọ pe awọn ti fa Taofeek le awọn ajọ to n ri sọrọ ijinigbe lorileede yii, National Agency For Prohibition On Trafficking In Person, NAPTIP, ẹka tiluu Oṣogbo lọwọ lati fọwọ ofin mu.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI