AbdulRazaq kẹdun iku Senetọ Ibarahim - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, April 17, 2024

AbdulRazaq kẹdun iku Senetọ Ibarahim


Kii ṣe iroyin tuntun mọ pe ọkan pataki lara awọn agba oloṣelu nipinlẹ Kwara, Sẹnetọ Rafiu Ibrahim ti jade laye.

Aarọ kutu oni, Ọjọru ni Sẹnetọ Ibrahim jade laye lẹni ọdun mẹrindinlọgọta, lẹyin asian rampẹ.

Nigba to n kẹdun iku oloogbe naa, Gomina AbdulRahman AbdulRazaq sọ pe ibanujẹ nla ni iku akikanju oloṣelu ọmọ ẹgbẹ Peoples Democratic Party, PDP naa jẹ.

AbdulRazaq ni iku Sẹnetọ Ibrahim ti jẹ ko ye gbogbo eeyan pe awayemalọ kankan ko si, ati pe nigba ti iku ba de, ko nii sọ fẹnikẹni.

Fun idi eyi, AbdulRazaq gba awọn eeyan lamọran lati maa ranti ọjọ iku, ki wọn si maa fi huwa rere lawujọ.

Bakan naa lo ba awọn mọlẹbi oloogbe ati awọn ara ijọba ibilẹ Ojoku ti Ibrahim ti wa kẹdun, pẹlu adura wi pe ki Ọlọrun mu wọn lọkan le.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI