Aiyedatiwa ati awọn mẹẹdogun miran ni yoo kopa ninu eto idibo abẹle APC l'Ondo lọsẹ yii - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, April 18, 2024

Aiyedatiwa ati awọn mẹẹdogun miran ni yoo kopa ninu eto idibo abẹle APC l'Ondo lọsẹ yii


Ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC nipinlẹ Ondo ti fi ontẹ luu Gomina Lucky Aiyedatiwa ti ipinlẹ naa, pẹlu awọn mẹẹdogun miran lati kopa ninu eto idibo gomina abẹle to n bọ lọna.

Ogunjọ, oṣu kọkanla, ọdun 2024 ni eto idibo gomina yoo waye nipinlẹ Ondo, ti awọn ẹgbẹ oṣelu si ti n mura silẹ lati kopa.

A gbọ pe igbimọ ẹlẹni meje to n ṣayẹwo awọn oludije, eyi ti Sẹnetọ Joshua Lidani jẹ alaga lo sọ awọn meje ti yoo kopa ninu eto idibo abẹle to n bọ lọjọ Abamatẹ, ọsẹ yii.

Lara awọn to yege naa Gomina Lucky Aiyedatiwa, Isaac Kekemeke to jẹ igbakeji alaga apapọ ẹgbẹ APC ni ẹkun Iwọ-Oorun; Olusọji Ẹhinlanwo, toun ti figba kan ri jẹ ọmọ ile igbimọ aṣofin; Olugbenga Edema, ati Sẹnetọ Jimọh Ibrahim.

Awọn miran ni Arabinrin Funmilayo Waheed-Adekojọ, Akinfọlarin Samuel, Adewale Akinterinwa, Oloye Oluṣọla Oke, Ohunyeye Felix ati Morayọ Lebi.

Bẹẹ tun ni Garvey Iyanjan; Ọjọgbọn Francis Faduyile, Arabinrin Judith Ọmọgoroye, Ifẹoluwa Oyedele ati Okunjimi John wa lara awọn ti ajọ naa fi ontẹ lu.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI