Bi iyawo mi ba loyun fun ọkunrin miran labẹ orule mi, mo ṣetan lati gba oyun ati ọmọ to ba bi - Baba Tee - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, April 15, 2024

Bi iyawo mi ba loyun fun ọkunrin miran labẹ orule mi, mo ṣetan lati gba oyun ati ọmọ to ba bi - Baba Tee


Gbajugbaja oṣere tiata nni, Babatunde Bernard Tayọ, ẹni ti ọpọ awọn ololufẹ rẹ mọ si Baba Tee ti sọ pe oun ṣetan lati gba oyun ati ọmọ ti iyawo oun ba bi fun ale labẹ orule oun.

O sọrọ yii lati jẹ ki awọn eeyan mọ erongba rẹ lori ayẹwo ojulowo baba ọmọ ti awọn oloyinbo n pe ni 'DNA', ti awọn eeyan n pariwo rẹ lori ayelujara lasiko yii.

Bi ẹ ko ba gbagbe, lati bii ọjọ meloo sẹyin ni awọn eeyan ti n sọrọ loriṣiriṣi nipa idi to fi dara ki awọn ọkunrin maa ṣayẹwo ẹjẹ àwọn ọmọ wọn, lati le mọ boya awọn gan-an ni ojulowo baba.

Nigba to n sọrọ nibi ifọrọwerọ pẹlu ileeṣẹ amohunmaworan TVC l'Ekoo, Baba Tee sọ pe o yẹ ki awọn obinrin lọ kọ bi wọn ṣe n kuro ninu igbeyawo ti ko ba tẹ wọn lọrun.

O ni kaka ki wọn maa fi lilu ninu igbeyawo kẹwọ lori gbigbe oyun ati ọmọ ale fun ọkọ wọn, ki wọn tete sa kuro.

Baba Tee ni ọpọ awọn obinrin lo n lu ọkunrin ni jibiti ọmọ lasiko yii lorileede yii nitori idi kan tabi omiran, lara rẹ si ni aile tẹ ara ẹni lọrun nipa ibalopọ.

O wa fi kun ọrọ rẹ pe oun le gba ọmọ ti ki ba a ṣe toun, iyẹn bi iyawo oun ba kabamọ pe oun gba pe oun jẹbi ẹsun agbere.

Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe 
“Awọn obinrin ko le maa lo iya ti wọn n jẹ nile ọkọ tabi lilu ṣe awawi lati maa fi lu ọkunrin ni jibiti ọmọ. Bi ọkọ yin ko ba kii ṣe yin daadaa, ẹ ba ẹsẹ yin sọrọ kuro ninu igbeyawo bẹẹ.

“Bi a ba n sọ nipa jibiti ọmọ, awọn obinrin ni wọn ni ẹbi naa. Ẹ ko le da ẹbi ru ọkọ nitori pe ko le loyun. Gẹgẹ bi obinrin, bi ẹ ba mọ pe ẹ ko le fi ara da iya ti ọkọ fi n jẹ yin, ẹ fi igbeyawo naa silẹ.

“Emi gẹgẹ bi ẹnikan, ko si ohun ti mi o le tọju fun obinrin to dara si mi. Bi obinrin ba yan mi jẹ, ti ọmọ si jade lati ibi iyanjẹ naa, ti mo si mọ, mo maa forijin to ba gba pe oun jẹbi. Mo maa gba ọmọ naa gẹgẹ bi ọmọ mi.”

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI