Ọwọ Amọtẹkun tẹ Babalọla to fi oruka igbadi ji iyale ile gbe l'Oṣogbo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, April 3, 2024

Ọwọ Amọtẹkun tẹ Babalọla to fi oruka igbadi ji iyale ile gbe l'Oṣogbo


Ọwọ ẹṣọ aabo ilẹ Yoruba ti a mọ si Amọtẹkun, ẹka tipinlẹ Ọṣun ti tẹ ọkunrin ẹni ọdun marundinlogoji kan, Babalọla Abayọmi Timothy lori ẹsun ijinigbe.
 
Gẹgẹ bi alakoso Amọtẹkun nipinlẹ naa, Ọgagunfẹyinti Bahsir Adewinmbi ṣe ṣalaye, o ni agbegbe Ode-Omu niṣẹlẹ ọhun ti waye.

Adewinmbi ni Sọfiyat, ẹni ọdun marundinlogoji ni Babalọla, ọmọ bibi ilu Modakẹkẹ fi oruka igbadi gba, ati pe agbegbe Ṣekona lọwọ ti tẹ ẹ.
 
Nigba to n sọrọ l'Ọjọru, ọsẹ yii, Adewinmbi sọ pe ọjọ kinni, oṣu yii lọwọ tẹ ọkunrin naa.
 
O ni ọsẹ mẹta sẹyin ni Babalọla ti gbe Sọfiyat sile rẹ, to si n ko ibasun fun un karakara lojoojumọ
 
Bẹẹ lo fi kun ọrọ rẹ pe awọn ti lọ fa Babalọla le ajọ ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ lọwọ fun iwadii kikun.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI