Itunu Aawẹ: Gomina AbdulRazaq b'awọn musulumi yọ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, April 8, 2024

Itunu Aawẹ: Gomina AbdulRazaq b'awọn musulumi yọ


Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti ba awọn ọmọ iya rẹ ninu ẹsin Islam yọ fun ti ayẹyẹ ipari aawẹ Ramadaani.

Bakan naa lo tun ki olori ẹlẹsin nipinlẹ Kwara, Ẹmir tiluu Ilọrin, Ọmọwe Ibrahim Sulu-Gambari pẹlu bi wọn ṣe pari aawẹ Ramadaani layọ ati alaafia.

Laisko to n ki wọn, o gba wọn niyanju lati yago fun iwa ọdaran ati aw]on iwa ti ko ba iwa ọmọluabi mu, bẹẹ lo ni ki wọn maa ṣe saara daadaa.

O ni ki wọn ba iṣọkan ati alaafia  laaye, ki wọn si farajin fun iṣẹ Ọlọrun Allah.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI