Finidi George di akọni-mọ-ọn-gba Super Eagles - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, April 29, 2024

Finidi George di akọni-mọ-ọn-gba Super Eagles


Awọn alakoso ajọ to n ṣakoso ere bọọlu lorileede Naijiria, Nigeria Football Federation lonii, ọjọ Aje ti kede gbajugbaja agbabọọlu nni, Finidi George gẹgẹ bi akọni-mọ-ọn-gba Super Eagles.

Oni ọjọ Aje ni ajọ NFF kede Finidi George gẹgẹ bii akọnimọ-ọn-gba naa, ti wọn si ni iṣẹ rẹ bẹrẹ loju ẹsẹ lai fi asiko ṣofo.

A gbọ pe lẹyin abajade ayẹwo ti igbimọ amuṣẹṣe, iyẹn Technical and Development Committee sọ erongba wọn lori ayẹwo wọn ni wọn kede ọkunrin naa.

Finidi George lo ti tukọ ẹgbẹ agbabọọlu Super Eagles ninu oṣu to kọja lasiko ifẹsẹwọnsẹ ọlọrẹ-sọrẹ to waye pẹlu orileede Morocco.

Ogun oṣu ni George fi jẹ igbakeji akọnimọn-ọn-gba tẹlẹ, José Pesiero kiyẹn to fi ẹgbẹ agbabọọlu ọhun silẹ lẹyin idije ife ẹyẹ ilẹ Afrika to waye ni Cote d'Ivoire, nibi ti wọn ti ṣe ipo keji.

Bi ẹ ko ba gbagbe, inu oṣu kọkanla, ọdun 2021 ni ẹgbẹ agbabọọlu Eyinmba yan George gẹgẹ bii akọnimọ-ọn-gba wọn, ti wọn si lo ko ipa ribiribi nibẹ.

O di ohun ti awọn eeyan n beere fun nigba ti Eyimba gba ife ẹyẹ idije ilẹ Naijiria ti a mọ si Nigeria Premier League.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI