Gomina AbdulRazaq bura fun Abọlọrẹ gẹgẹ bii Kọmiṣanna f'ọrọ ohun alumọni ni Kwara - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, April 29, 2024

Gomina AbdulRazaq bura fun Abọlọrẹ gẹgẹ bii Kọmiṣanna f'ọrọ ohun alumọni ni Kwara


...Bẹẹ lo tun bura fun AbdulQuawy Olododo gẹgẹ bi Kọmiṣanna f'ọrọ eto iṣẹ ode ati igbokegbodo ọkọ 

Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti ipinlẹ Kwara ti bura fun Ọmọwe Alabi Afeez Abọlọrẹ gẹgẹ bii kọmiṣanna f'ọrọ awọn ohun alumọni nipinlẹ naa, to si n gba a níyànjú lati ṣiṣẹ takuntakun fun idagbasoke ati ilọsiwaju.

Oni ọjọ Aje ni gomina ṣeto ibura naa niluu Ilọrin, iyẹn ni ọfiisi rẹ.

Yatọ si Abọlọrẹ ti gomina bura fun, o tun bura fun Onimọ-ẹrọ AbdulQuawiy Olododo gẹgẹ bii kọmiṣanna f'ọrọ iṣẹ ode ati igbokegbodo ọkọ 

Ṣaaju asiko yii, gẹgẹ bi a ṣe gbọ, Ọmọwe Abọlọrẹ ti kọkọ ṣe kọmiṣanna f'ọrọ eto ẹkọ giga (Tertiary Education).

Lara awọn to wa nibi eto ibura ọhun ni akọwe ijọba, Ọjọgbọn Mamman Saba Jibril; olori awọn oṣiṣẹ gomina, Ọmọọba AbdulKadir Mahe; Oludamọran agba, Alaaji Sa'adu Salau; Alakoso ileeṣẹ NNPCL, Ọmọwe Ghali Alaya.

Awọn miran ni Amugbalẹgbẹ agba pataki lori ọrọ ẹsin Islam, Alaaji Ibrahim Danmegoro; alaga ẹgbẹ oṣelu APC lagbegbe Ilọrin East, Kọmureedi Habib Lawal.

Awọn yooku ni Alaaji Abdulrazhaq Jiddah; Baale Iponrin, Alaaji Ahmad Musa; Alhaji L'Aziz A.K Jimoh; Hajia Muinat Ibrahim; ati awọn miran.

Lara awọn ohun ti wọn fi yan awọn kọmiṣanna tuntun naa ni ọkan akikanju lati sin ilu abinibi wọn, pẹlu erongba wi pe wọn yoo tun ṣe daadaa ju ti atẹyinwa lọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI