Ọwọ ọlọpaa tẹ afurasi mẹrin to pa iyale ile fun etutu aje n'Ibadan - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, April 19, 2024

Ọwọ ọlọpaa tẹ afurasi mẹrin to pa iyale ile fun etutu aje n'Ibadan


Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun ti sọ pe ọwọ awọn ti tẹ afurasi mẹrin ti wọn ṣe iku pa iyale ile ẹni ọdun marundinlaadọta kan niluu Ibadan, ipinlẹ Ọyọ.

Yẹmisi Ọpalọla to jẹ agbẹnusọ ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun lo sọ eyi di mimọ niluu Oṣogbo loni, ọjọ Ẹti.

O ni awọn mu awọn mẹrin naa lẹyin ti ọmọ oloogbe wa fi to wọn leti pe awọn n wa iya oun.

Ninu atẹjade ti Ọpalọla fi sita, o ni ọjọ kejidinlogun, oṣu kẹta, ọdun yii ni wọn wa fi to ileeṣẹ ọlọpaa ẹkun Apomu leti wi pe wọn n wa Arabinrin Aminat Usman.

Ọmọ obinrin naa lo sọ pe iya oun kuro nile ni nnkan bi agogo mẹwaa owurọ, ọjọ kẹtala, oṣu kẹta, ṣugbọn ti wọn ko gburo rẹ latigba naa.

Ọmọ naa sọ pe lyana Ajia-Ibadan ni mama oun dagbere lati lọ wo ẹnikan to n jẹ Onifade Oyekanmi, ṣugbọn ti ẹrọ ibanisọrọ rẹ ko lọ latigba naa.

Ọpalọla ni ọmọ naa ṣalaye pe oun nigbagbo pe Oyekanmi to jẹ babalawo mọ nipa bi mama oun ṣe poora.

Lẹyin eyi ni Ọpalọla sọ pe awọn lọ gbe Oyekanmi nile, ti wọn si tare ẹjọ naa si ẹka to n ri si ọran State Criminal Investigation Department, niluu Oṣogbo.

Siwaju sii lo ni Oyekanmi jẹwọ fun wọn, eyi lo si fa bi ọwọ ṣe tẹ awọn mẹta yooku, ti wọn si ṣalaye bi wọn ṣe pa obinrin naa fun etutu aje

Nigba ti wọn lọ yẹ ile wọn wo, oriṣiriṣi nnkan abami bii igo to kun fun awọn nnkan dudu, eyi ti wọn fura si pe ẹya ara ni wọn jo sinu rẹ, ada meji, ikọkọ nla.dudu ati awọn ọṣẹ dudu ni wọn ba nibẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI