Ijọba Kwara ra ẹrọ amunawa igbalode to n lo oorun 'Inverter' si ọsibitu Ṣobi - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, April 19, 2024

Ijọba Kwara ra ẹrọ amunawa igbalode to n lo oorun 'Inverter' si ọsibitu Ṣobi


Lojuna lati dẹkun gbogbo wahala idakureku ina ijọba, ati lati mu idagbasoke ba ọrọ eto ilera araalu, ijọba ipinlẹ Kwara ti ra awọn irinṣẹ ero amunawa igbalode to n lo oorun, eyi ti oloyinbo n pe ni Inverter' si ọsibitu awọn akọṣẹmọṣẹ, iyẹn Sobi Specialist Hospital.

Ero amunawa ọhun ni wọn ni agbara rẹ jẹ 50KVA, eyi ti yoo gbe awọn irinṣẹ ti wọn n lo lati fi ṣiṣẹ, paapaa iṣẹ abẹ.

Bakan naa, Gomina AbdulRahman AbdulRazaq tun buwọ lu pe ki wọn tun lọ ṣe ina igbalode yii ti agbara rẹ to 25KVA si awọn wọọdu ti wọn ti n gba ẹbi (maternity), tọju awọn to ni ijamba ati iṣẹlẹ pajawiri.


Dokita Abdulraheem Malik, to jẹ akọwe agba nileeṣẹ to n ri sọrọ ile iwosan, Kwara State Hospitals Management Board, lo lewaju ikọ to lọ wo awọn irinṣẹ tuntun naa.

Ni bayii, a gbọ pe idakureku ina mọnamọna ti di ohun igbagbe patapata, nitori pe wakati mẹrinlelogun to wa ninu ọjọ ni yoo maa fi ṣiṣẹ lai dawọ duro.

Bakan naa la tun gbọ pe awọn ilu bii Lafiagi, Kaiama, Patigi, Okuta, Ilesa-Baruba, Yashikira, ati Sobi Specialist ni wọn tun ti n gbaradi lati ṣe awọn ina igbalode yii si.


No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI