Opopona Ekoo si Calabar, akanṣe iṣẹ ti ko ni ẹlẹgbẹ ni - Gomina AbdulRazaq - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, April 19, 2024

Opopona Ekoo si Calabar, akanṣe iṣẹ ti ko ni ẹlẹgbẹ ni - Gomina AbdulRazaq


Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti ipinlẹ Kwara ti sọ pe akanṣe iṣẹ ti ko ni ẹlẹgbẹ tabi alatako ni opopona marosẹ ẹẹdẹgbẹrin kilomita (700km) Ekoo si Calabar ti ijọba apapọ dawọ le.

AbdulRazaq ni bi akanṣe iṣẹ ọhun yoo ba fi pari, yoo ni ipa rere lorileede Naijiria.

Gomina ipinlẹ Kwara, ẹni to tun jẹ olori awọn gomina Naijiria lo sọrọ naa laipẹ yii lasiko toun pẹlu awọn gomina ati awọn adari ile igbimọ aṣofin lọ ṣabẹwo si Aarẹ Tinubu nile rẹ to wa niluu Ekoo.
 
Lara awọn to tun wa nibẹ ni igbakeji Aarẹ, Kashim Shettima; Aarẹ ile igbimọ aṣofin, Godswill Akpabio; Aarẹ ile igbimọ aṣofin kekere, Tajudeen Abass ati awọn miran.

Nibẹ lo ti gbe oriyin fun Aarẹ Tinubu wi pe aṣiwaju to ṣee fi ọkan tan ni, ati pe yoo mu awọn ileri rẹ ṣẹ fun araalu.

Igbesẹ yii ni AbdulRazaq tun fi kun ọrọ rẹ pe yoo mu idagbasoke nla ba eto ọrọ rẹ orileede Naijiria.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI