Adajọ agba mejila ni Kwara gba mọto bọginni olowo nla - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, May 3, 2024

Adajọ agba mejila ni Kwara gba mọto bọginni olowo nla


Orin ayọ lo n jade lẹnu awọn adajọ agba mejila kan nipinlẹ Kwara, nigba ti Gomina AbdulRahman AbdulRazaq fa kọkọ ọkọ ayọkẹlẹ jiipu le wọn lọwọ lati maa fi ṣe ẹsẹ rin.

Ṣaaju asiko yii ni awọn adajọ agba marun-un kan ti kọkọ gba jiipu olowo nla, iyẹn ninu oṣu keji, ọdun yii.

Adajọ mọkanla lo gba jiipu Toyota Fortuner lati fi mọ riri iṣẹ ti wọn n ṣe, paapaa lori ipo ti wọn di mu.
 
Bẹẹ ni adajọ agba pata nipinlẹ naa, Onidajọ Abiọdun Ayọdele Adebara gba jiipu Toyota Land Cruiser to jade lọdun 2024 fun lilo rẹ, gẹgẹ bii ipo to di mu.

Ohun ti a gbọ ni pe eto yii ti wa lara eto iṣuna ọdun 2023.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI