Sanwo-Olu sọ Damilọla, ọmọ Wasiu Ayinde di amugbalẹgbẹ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, May 3, 2024

Sanwo-Olu sọ Damilọla, ọmọ Wasiu Ayinde di amugbalẹgbẹ


Gomina Babajide Sanwo-Olu ti sọ ọkan lara awọn ọmọ gbajugbaja olori Fuji nni, Wasiu Ayinde ti ọpọ awọn eeyan mọ si KWAM1 De Ultimate di amugbalẹgbẹ.
 
Damilọla Marshall ni orukọ ọmọ Wasiu Ayinde naa ti Sanwo-Olu yan gẹgẹ bi amugbalẹgbẹ lori eto irin ajo afẹ nipinlẹ Ekoo.

Wasiu Ayinde lo sọ eyi di mimọ funra rẹ lode ariya kan to ti lọ kọrin laipẹ yii, nibẹ lo si ti ni ki awọn eeyan maa ba oun ki gomina Ekoo, fun bo ṣe da oun lọla nipa ọmọ oun.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI