Alakoso ileeṣẹ ọgba ẹwọn ni Kwara ku lojiji - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, May 26, 2024

Alakoso ileeṣẹ ọgba ẹwọn ni Kwara ku lojiji


Alakoso agba fun ileeṣẹ ọgba ẹwọn nipinlẹ Kwara, Adeyinka Oyun ti jade laye.

Atẹjade ti agbẹnusọ ileeṣẹ ọgba ẹwọn nipinlẹ naa, Adegbulugbe Olumide lo fidi iroyin naa mulẹ lọjọ Abamẹta to kọja.

Ojiji ni wọn sọ pe Adeyinka ku laarọ ọjọ Abamẹta tii ṣe Satide naa.

Nibẹ lo ti ṣalaye pe oloogbe naa ṣi wa ni ibi-iṣẹ titi di nnkan bi agogo mẹfa aabọ irọlẹ, ọjọ Ẹti.

“A kabamọ lati kede iku ojiji alakoso Adeyinka Adebayọ Oyun, ẹni to jade laye laarọ oni, Satide, ọjọ karundinlọgbọn, oṣu karun-un, ọdun 2024.

“Titi to fi jade laye, oun ni alakoso agba fun ileeṣẹ ọgba ẹwọn nipinlẹ Kwara. AA. Oyun wa ni ọfiisi titi di agogo mẹfa irọle, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu karun-un, ọdun 2024.

“Iku ojiji jẹ adanu nla fun gbogbo oṣiṣẹ ileeṣẹ wa. O jẹ ẹni to fara si iṣẹ, akikanju to si gbajumọ iṣẹ rẹ, pẹlu pe o tun jẹ ẹni ti kii fi ohunkohun pamọ.
“A maa kede eto isinku rẹ laipẹ.”

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI