'Ẹní dádé ti kúrò lọ́modé' - DJ Cuppy - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, May 25, 2024

'Ẹní dádé ti kúrò lọ́modé' - DJ Cuppy


Gbajugbaja onkọrin takasufe nni, Florence Ọtẹdọla ti sọrọ to ya awọn ololufẹ rẹ, paapaa awọn to tun jẹ ọmọ Yoruba lẹnu.

Ko si ohun meji to mu ki ọrọ ti Florence Ọtẹdọla, ẹni ti ọpọ awọn ololufẹ rẹ mọ si DJ CUPPY lẹnu ni pe ko sẹni to lero wi pe o gbọ ede Yoruba.

DJ Cuppy jẹ ọmọ gbajugbaja olowo nni, Fẹmi Ọtẹdọla, to si jẹ pe ilẹ Gẹẹsi ni wọn bii si.

Lọsan oni lo kọ ọ soju opo ayelujara ti Facebook rẹ pe;
"Ení dádé ti kúrò lómodé 👑".

Ọrọ to kọ yii jọ awọn eeyan loju gidi, pẹlu bo tun ṣe fi aami sori ọrọ naa.


No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI