Arsenal kede agbabọọlu mejilelogun to fi ẹgbẹ agbabọọlu wọn silẹ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, June 3, 2024

Arsenal kede agbabọọlu mejilelogun to fi ẹgbẹ agbabọọlu wọn silẹ


Ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal ti kede sita pe awọn agbabọọlu ti ko din ni mejilelogun lo fi ẹgbẹ agbabọọlu wọn silẹ.
 
Arsenal ni ipari saa yii ni iwe adehun ti wọn tọwọ bọ dopin.
 
Awọn alakoso Premier ni kede eyi loni ọjọ Aje ninu atẹjade ti wọn fi sita.
 
Ninu atẹjade ọhun, wọn ni “A n sọ pe o dabọ fun awọn agbabọọlu ọkunrin ati ọjọgbọon wọnyi, bẹẹ si lawọn agbabọọlu obinrin ti a ti kede tẹlẹ naa n  lọ.
 
Awọn naa ni, Mauro Bandeira, Omari Benjamin, Luis Brown, Catalin Cirjan, Noah Cooper, Sabrina D’Angelo, Henry Davies, Ovie Ejeheri, Mohamed Elneny, Taylor Foran, Hubert Graczyk, James Hillson, Henry Jeffcott, Tyreece John-Jules,
 
Awọn yooku ni; Alex Kirk, James Lannin-Sweet, Kaylan Marckese
Vivianne Miedema, Arthur Okonkwo, Kamarni Ryan, Cedric Soares
ati Kido Taylor-Hart.
 
Bakan naa ni wọn fi kun un pe ọgbọn ọjọ ninu oṣu kẹfa, ọdun yii ni adehun ọhun yoo dopin patapata.
 
Awọn agbabọọlu obinrin ọhun ni Amario Cozier-Duberry, Karl Hein and Reuell Walters.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI