Wo awọn idi pataki ti CBN fi gba iwe aṣẹ lọwọ ile ifowopamọ Heritage - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, June 3, 2024

Wo awọn idi pataki ti CBN fi gba iwe aṣẹ lọwọ ile ifowopamọ Heritage


Lonii, ọjọ Aje, ọjọ kẹta, oṣu kẹfa, ọdun 2024 ni ile ifowopamọ agba lorileede Naijiria, Central Bank of Nigeria kede sita pe awọn ti gba iwe aṣẹ lati maa ṣiṣẹ gẹgẹ bi ile ifowopamọ lọwọ Heritage Bank Plc.

Ninu atẹjade ti CBN gbe soju opo X wọn laarọ oni, wọn jẹ ko di mimọ pe ko si ipadasẹyin ninu gbigba iwe aṣẹ naa.

Latigba ti CBN ti kede iroyin yii ni awọn eeyan ti n beere idi pataki ti CBN fi gbe igbesẹ naa.

Ṣugbọn ninu atẹjade CBN, ti Sidi Ali to jẹ alakoso eto iroyin fi sita, lara ẹsun ti wọn fi kan ile ifowopamọ Heritage ni pe wọn ko ṣiṣẹ de gbedeke to yẹ lati fi mu ilọsiwaju ba eto iṣuna wọn, to si n dunkooko mọ iduro ṣinṣin wọn gẹgẹ bi ole ifowopamọ.

Wọn ni ọpọ igba ni igbimọ awọn igbimọ olulanilọyẹ ti gbe igbesẹ lati fi ran awọn alakoso ile ifowopamọ Heritage lọwọ, ṣugbọn to jẹ pe pabo lo ja si.

CBN ni lati le jẹ ki awọn araalu ati onibara ni igbagbọ ati igboya nipa didowopọ pẹlu ile ifowopamọ, awọn ni lati daabo bo agbekalẹ ilana ile ifowopamọ.No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI