Ṣọọṣi MFM kọ lo ju Fẹmi Jimoh sẹwọn ọdun mẹsan-an, ko rẹni gba beeli rẹ ni - Awọn alakoso - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, June 8, 2024

Ṣọọṣi MFM kọ lo ju Fẹmi Jimoh sẹwọn ọdun mẹsan-an, ko rẹni gba beeli rẹ ni - Awọn alakoso


Ile ijọsin Mountain of Fire and Miracles Ministries (MFM) ti ṣapejuwe ọrọ ti ọkan ninu awọn Pasitọ ṣọọṣi naa tẹlẹ sọ ninu fọnran kan to n ja rain-rain lori ẹrọ ayelujara, gẹgẹ bi irọ funfun balau.

Ṣọọṣi ọhun sọ pe, o pẹ ti ọkunrin Pasitọ naa, ti wọn pe orukọ rẹ ni Fẹmi Jimoh ti maa n wu iwa laabi, ni gbogbo ijọ ti wọn ba gbe e lọ ṣe adari. Eyi lo mu ki wọn gbe e pada wa si olu ile ijọsin naa lati fi da sẹria fun, gẹgẹ bi ohun ibawi, nireti pe yoo yi iwa rẹ pada. 

Ọrọ ti ọkunrin naa n sọ kiri naa to n jo kiri bi ina, ti n mu awuye-wuye dani, o si mu ki awọn araalu fi oju buruku wo ileejọsin naa. 

Ṣugbọn, ninu ọrọ ti ileejọsin naa fi ranṣẹ si awọn oniroyin, lopin ọsẹ to kọja, wọn fi to wa leti pe ọkunrin yii, Jimoh, ati ojugba rẹ, tiyẹn n jẹ Caleb Ọlọruntẹlẹ, ti n gbero bi wọn ṣe maa ja ileejọsin naa lole, ki wọn si gbe owo ọrẹ ti wọn pe ni akọso lọ.

Nigba ti wọn n ba awọn oniroyin sọrọ ni olu ileejọsin naa lọjọ Ẹti, Fraide, Agbẹjọro ṣọọṣi naa, Ọgbẹni Davidson Adejuwọn, sọ pe irọ ti awọn ọkunrin mejeeji wọnyi n pa kiri, jẹ eyi to n kọ ileejọsin naa lominu, nitori ko si ootọ kan nibẹ rara. 

Lara awọn irọ ti awọn ọmọkunrin wọnyi n pa kiri, gẹgẹ bi Adejuwọn ṣe sọ fun wa, ni pe; ṣe ladari ileejọsin naa ti oun mọle fun odidi ọdun mẹsan-an, gbogbo ẹbẹ iya oun lọdọ adari ijọ naa, pabo lo ja si.  

Adejuwọn tun sọ pe ohun to ṣẹlẹ ni pe ileẹjọ gba beeli rẹ, ṣugbọn ọkunrin naa ko ri ẹni gba beeli rẹ rara. 

"Ohun taa lero pe o yẹ ki Ọgbẹni Jimoh atawọn mọlẹbi rẹ ṣe ni pe ki wọn wa ẹni to maa gba beeli fun wọn, bẹẹ ko sọrọ owo ninu beeli yii rara, gẹgẹ bi awọn lọọya kan ti n gbe e pooyi ẹnu kiri. 

"Njẹ ko ya yin lẹnu pe ohun ti wọn n sọ kiri pe Pasitọ Daniel Olukọya, to jẹ olori ijọ MFM lo ti awọn mọle fun odidi ọdun mẹsan-an, nigba to jẹ pe ileẹjọ fun wọn ni beeli, awọn to si yẹ ko gba beeli wọn ko ṣe bẹẹ, ewo ni ti Olukọya nibẹ?

"Ileejọsin to ni laari ni ijọ MFM, wọn si mọ bi a ti n tọju awọn olujọsin gbogbo to wa nileejọsin naa daadaa. Gbogbo igbiyanju wọn lati bu ẹnu atẹ lu ohun ti ileejọsin naa n ṣe ko le bori rara, nitori ijọ Ọlọrun ni.  

"Ẹtọ wa ni lati sọ fun awọn agbofinro ohun ti ko ba lẹtọọ to n ṣẹlẹ ninu ijọ naa, ohun ti a si ṣe naa niyẹn. Ohun gbogbo to ṣẹlẹ lẹyin yẹn, kii ṣe ohun to kan ileejọsin naa rara, ọrọ ileẹjọ ni, ọrọ naa ti kuro lọwọ ṣọọṣi, o ti di ọrọ ijọba. 

"Kii ṣe Olukọya lo ju Jimoh ati ojugba rẹ sẹwọn ọdun mẹsan-an, iwa rẹ ni, adajọ lo si paṣẹ bẹẹ. Ko si nnkan to kan ṣọọṣi ninu aṣọle to n tojubọle lọ sọdọ awọn babalawo kiri, iyẹn ko kan wa rara."
 
Lara awọn ti Jimoh lọọ bẹ lọwẹ pe ki wọn waa darapọ mọ oun lati ja ṣọọṣi lole, ṣalaye bi wọn ṣe ka gbogbo ohun ti wọn jọ sọ silẹ sinu fọnran fun awọn agbofinro. 

Akeem Mọmọdu ti wọn n pe ni Ọmọjọmọlọ, Ọgbẹni Adebayọ Fatai, ti wọn n pe ni Aboki ati Ọgbẹni Tajudeen Oseni ti wọn n pe ni Orji ṣalaye fun awọn agbofinro pe Jimoh lero pe awọn fọwọsowọpọ pẹlu rẹ ninu iṣẹ ibi naa, ṣugbọn ko mọ pe awọn fẹẹ mu u lọrun ọwọ ni.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI