Lara awọn ti gomina bura fun ni Oludamọran pataki meji, oluṣiro owo agba tuntun, ati akọwe agba meje.
Awọn wọnyi, gẹgẹ bi a ṣe gbọ, ni yoo ba gomina ṣiṣẹ papọ ninu iṣakoso ẹlẹẹkẹji to n lọ lọwọ yii.
Lara awọn alabaṣiṣẹpọ tuntun naa ni: Alaaji Abdulrazaq Jiddah (SA Special Duties); Ambassador Umulkhaer Onaolamipo Ahmed Alaye (SA Civic Engagement); ati Alayande Fatai (Auditor General).
Awọn akọwe agba tuntun ọhun ni: Afolabi Olaitan (Energy); Shittu Olufunke Mercy (Service Welfare); Abdulazeez Tinuke Risikat (Housing and Urban Development); Taoheed Abdullahi Ayodeji (Health); Abu Anthony Gana (Works); Salau Kabiru Abdullahi (Transportation); ati Yahya Muhammed (Livestock Development).
Nibi eto ibura naa ni gomina ti rọ gbogbo wọn lati fi ọkan itara ati ẹmi Ọlọrun ṣiṣẹ isin ilu, ki wọn ma si ṣe lo ipo wọn lati ṣojusaaju ẹnikẹni.
“Iyansipo yin ti gbe e yin sipo anfaani lati sin Ọlọrun ati ọmọniyan, lati mu ki nnkan dara ju bi ẹ ṣe ba a lọ, ati lati kopa ninu idagbasoke ipinlẹ wa pẹlu ipo ileeṣẹ tuntun ti ẹ gba,” Gomina sọ eyi nibi eto ibura naa.
No comments:
Post a Comment