Lara awọn erongba ati akitiyan Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti ipinlẹ Kwara ni ki gbogbo araalu maa gbe igbe aye alaafia ti ko nii ni wọn lara, eyi lo mu iṣakoso re gunle ṣíṣe awọn ohun ti yoo mu idẹrun ba gbogbo olugbe ipinlẹ naa.
Igbokegbodo ọkọ to ja geere naa wa nibẹ, eyi si jẹ gomina logun gidi, to fi bẹrẹ awọn atunṣe si awọn opopona to ti dẹnukọlẹ tipẹ.
Kolonka lawọn opopona ti gomina ti ṣe kaakiri ilu ati igberiko to so ipinlẹ naa papọ, lai fi ti oṣelu tabi ọrọ iwa ẹlẹyamẹya ṣe.

Ninu atẹjade ti amugbalẹgbẹ pataki fun gomina lori eto iroyin igbalode, Kọmureedi Olayinka Fafoluyi tọpọ mọ si Solace fi sita lọjọ Iṣẹgun to kọja, o ni opopona Ibrahim Taiwo si Popo Road, eyi to wa ni ijọba ibilẹ Offa ti fẹẹ pari.
Fafoluyi sọ pe ipele karundinlọgọrun (95%) ni opopona ọhun de bayii lati pari.
Siwaju sii lo ni opopona yii wa lara awọn opopona to gun ju ni Kwara, eyi ti iṣakoso Gomina AbdulRazaq dawọ le, pẹlu erongba lati ṣagbelarugẹ fun eto ọrọ aje ipinlẹ naa, ati araalu lapapọ.
Solace, gẹgẹ bi ọpọ ṣe maa n pe e, ṣalaye pe opopona yii kii ṣe lati dẹkun idakureku ọkọ, ijamba, bi ko ṣe pe yoo tun mu imugbooro ba eto ọrọ aje ijọba ibilẹ naa, ti awọn ọlọja lati agbegbe miran yoo si maa rin lai daamu.