Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ti sọ pe ọwọ awọn ti tẹ afurasi ti ko din ni mẹjọ lori ikọlu awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun to waye ninu ọgba ile-ẹkọ giga ti Yaba nipinlẹ Eko, iyẹn Yaba College of Technology.
Ọjọ Iṣẹgun, Tuside, ọsẹ yii tii ṣe ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kẹrin, ọdun 2025 lawọn ọmọ ẹgbẹ okunkun doju ija kọ ara wọn, ti wọn si tun pa ara wọn nipakupa, ninu ọgba ile-ẹkọ giga naa.
Lara awọn tọwọ tẹ naa ni Adeyemo Abdulsamad, ẹni ọdun mẹrinlelogun ti wọn tun n pe ni Cloud; Afeez Enitan, ẹni ọdun mejidinlọgbọn; Ayomide Daniel, ẹni ọgbọn ọdun; Olamilekan Adeagbo, ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn ti wọn tun n pe ni Skinny.
Awọn yooku ni Mayor Samson, ẹni ọdun mejidinlọgbọn; Basit Ishola, ọmọ ogun ọdun; Quadri Sikiru, ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn ati Mariam Salihu toun jẹ ọmọ ọdun mẹtalelogun.
Ọlọpaa sọ pe oriṣiriṣi awọn nnkan ija oloro l'awọn gba lọwọ awọn afurasi tọwọ tẹ ọhun, ati pe wọn ti wa lahamọ, nibi ti wọn ti n fọrọ wa wọn lẹnu wo.
Ibọn ilewo Barreta kan, ibọn gigun 9mm, agba ọta ibọn, aake dudu meji ati ada meji ni gbogbo nnkan ti wọn gba lọwọ wọn.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa Eko, Benjamin Hundeyin, sọ pe bo tilẹ jẹ pe iwadii ṣi n tẹsiwaju nipa awọn tọwọ tẹ ati awọn tọwọ ṣi maa tẹ, sibẹ, o jẹ ko di mimọ pe gbogbo awọn tọwọ tẹ naa ni yoo foju winna ofin.
Iroyin to tẹ wa lọwọ jẹ ko di mimọ pe akẹkọọ kan ni wọn yinbọn pa lẹyin to pari idanwo lọsẹ to kọja.
No comments:
Post a Comment