Ẹni tọwọ ba tẹ nibi to ti n ta idọti sinu kọta yoo fẹnu fẹra bi abẹbẹ - Ijọba Kwara ṣekilọ faraalu - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, April 30, 2025

Ẹni tọwọ ba tẹ nibi to ti n ta idọti sinu kọta yoo fẹnu fẹra bi abẹbẹ - Ijọba Kwara ṣekilọ faraalu


Ijọba ipinlẹ Kwara ti ṣe ikilọ nla fawọn araalu lati dẹkun dida idọti sawọn oju ọna ti omi ati agbara n gba kọja, iyẹn inu kọta kaakiri ipinlẹ naa, pẹlu ileri wi pe ẹnikẹni tọwọ palaba rẹ ba seyi yoo foju winna ofin ijọba.

Eyii ni lati dẹkun iṣoro omiyale ati agbara ya ṣọọbu, eyi to tun ṣee ṣe ko mu ẹmi ati dukia lọ.
 
Ọga agba nileeṣẹ to n ri sọrọ eto imọtoto ayika ati agbegbe, Kwara State Environmental Protection Agency (KWEPA), Hajia Idayat Folorunsho lo sọrọ naa di mimọ laipẹ yii niluu Ilọrin.

Folorunsho ti alakoso agba ni ẹka ilẹ didanu ti a mọ si Waste Management, Arabinrin Tajudeen Fasilat Feyisayo ṣoju fun nigba to n sọrọ, jẹ ko di mimọ pe akoba nla ni dida itọdi soju ọna omi maa da silẹ laaarin ilu.

Nigba to n sọrọ nibi eto ilanilọyẹ to lewaju ṣe lọ saarin ilu, o lo ṣe pataki fun awọn eeyan lati mọ pataki imọtoto, nitori to n dena ajakalẹ arun oniruuru.

"Nigba ti oju ọna omi ba ti di, omi yoo wa ọna miran ti yoo gba, eyi to le ṣakoba fun ẹmi ati dukia. A rọ awọn araalu lati forukọ silẹ pẹlu awọn to n da ilẹ nu, ki wọn le maa wa lati ko ilẹ wọn loore-koore," Tajudeen sọ bẹẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI